Weird places and animals: Ẹ wo Ajá tó ń gbọ́ òórùn àìsàn ibà, ẹja tí a ko gbọdọ̀ pa àti ọọọ̀nì tó ń gbọ́ àdúrà ní Ìbàdàn

Airijinna lai ri abuke ọkẹrẹ ni Yoruba a maa sọ.

Bi eeyan ba de igbo to to igbo, yoo ri ẹranko to n tiro.

Nkan aramọnda orisi ni oju ti ri lẹnu igba ti awa naa ti n gbe ile aiye.

Laipẹ yi ni a ri iroyin to ja ranyin kaakiri pe igi kan to wo pa awọn eeyan ti o wu nidi ti tun sọji dide pada.

Awọn nkan wọn yi jẹ ohun to ṣe ni leemọ ti ọpọ ko si ribi ṣe alaye ohun to le fa iru iṣẹlẹ naa.

BBC ṣe akojọpọ awọn nkan awamaridi paapa to ni ṣe pẹlu ẹranko to wa layika wa.

Die ree ninu wọn:

Ẹja inu odo ti a ko gbọdọ pa

Ilu Aawẹ nipinlẹ Oyo ni Guusu Naijiria ni adagun odo Sogidi wa nibi ti awọn eeyan ko ti gbọdọ pa ẹja to wa ninu rẹ.

Awọn ẹja yi ti wa ninu odo naa lati dun 1750.

Ẹja wọnyi yi kii ṣe ẹja lasan, ko ṣẹja ko ṣe eeyan ni wọn.

Orisi ẹja ati eewọ lo rọ mọ awọn ẹja to wa ninu odo yi ti awọn to n ṣamojuto odo naa si sọ fun BBC ohun toju awọn to ja ẹja ri .

Ọoni to n gbọ adura awọn eeyan ni Ibadan

Alaye ti a gbọ lati ẹnu Oloye Raufu Yesufu to jẹ mọgaji ile Delesolu ti wọn ti n sin ọọni yi ni Ibadan ni pe igbẹ ọọni yi ti di oogun ara lile fawọn eeyan kan.

O ṣe ẹyin naa ni kayeefi abi?

Bẹẹ lo ṣe ri fun ọpọ eeyan to ba ṣalabapade ọọni yi ti babanla awọn to n sin bẹrẹ si ni tọju rẹ lati ọdun 1940 ninu ile.

Loju awọn ọmọ inu ile Delesolu, aṣa ni kii ṣe ẹsin rara toripe wọn gba pe ko si awo kan lawo ẹwa lori ọọni naa.

Ijapa alagba to lo ọdun 344 laye nilu Ogbomosho

Bi a ba ni ki a fi ti imọ ọde oni wo, ko yẹ ki ijapa Ogbomoso to ti wa pada jade laye pẹ to bo ti ṣe p to laye ki o to pada ku.

Baba Kabiyesi oni to jẹ Jagunjagun lo pade rẹ leti igbo to si mu wale latoju ogun.

Alagba ni orukọ rẹ, o ni awọn oṣiṣẹ lati aafin Kabiyesi to n tọju oun nikan.

Oṣiṣẹ meji tabi ju bẹẹ́ lọ lo n tọju oun nikan nigba to wa laye.Koda,lati kekere ni awọn kan ti n tọju rẹ ti wọn si dagba sẹnu ẹ.

Gbogbo ounjẹ ti eniyan n jẹ loun naa n jẹ to fi mọ eso bii Ọpẹ Oyinbo, Ibẹpẹ,Ọgẹdẹ. bakan naa, o n jẹ Amala, Irẹsi, Dodo ati Ẹwa ati bẹẹ bẹẹ lọ.

Ajá n gbọ́ òórùn àìsàn ibà

Kayeefi eleyi jẹyọ latara iwadii kan ti awọn onimọ sayẹnsi ṣe to fi han pe awọn aja le gboorun aisan iba lara eeyan.

Ojọgbọn Steve Lindsay ti fasiti Durham ni ilẹ̀ United Kingdom, lo ṣe agabtẹru iwadii naa nibi ti wọn ti lo ìbọ̀sẹ̀ àwọn ọmọde mẹta lati orilẹ-ede Gambia.

O fidi ẹ mulẹ pe bi ẹfọn to n fa àìsaǹ ibà ṣe maa n gboorun naa ni o ti han pe àwọn ajá naa n gboorun.

Ọjọgbọn Steve fidi ẹ mulẹ pe kẹmikaa kan maa n jade lára ẹni to ba ni aisan ibà ni eyi ti awọn ajá naa le gbọ oorun rẹ lara eniyan.

Ìbọ̀sẹ̀ àwọn ọdọmọde naa ni wọn lò fun iwadii yii ni eyi ti àwọn aja naa gba meje ninu mẹwaa dàadáa.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Ti awọn ẹranko la sọ tan yi, ẹ jẹ ki a wo awọn aaye aramọnda ti awọn eeyan agbegbe ibi ti wọn wa maa n foju abami wo wọn.

Ikogosi nibi ti omi tutu ati gbigbona ti n jade ninu ilẹ

Ilu ikọgọsi Ekiti lo gbajugbaja, to si tun jẹ ibudo igbafẹ nitori omi odo kan to nmu omi gbigbona ati tutu jade.

Gẹgẹbi ẹnikan to sọrọ nipa odo naa ti wi, tiyale-tiyawo (Awọ ati Awẹle) ni wọn di omi Ikọgọsi.

O ni awọn eeyan maa nwa lati origun mẹrẹẹrin agbaye ni ojoojumọ lati bu omi Ikọgọsi fun iwosan.

Omi ori oke to da duro ni Ado awaye

Yatọ si Colorado ni orileede Amẹrika, ilu Ado Awaye ni ipinlẹ Oyo ni adagun omi ori apata tun wa lagbaye.

Ko kun ri ko lọ ilẹ si toun ti bi ojo ba ṣe le rọ to,Ado awaye jẹ ibudo ti ọpọ eeyan maa n ṣe eemọ ti wọn ba de ibẹ.

Ogbeni Ayo Adams to jẹ alakoso irinajo afẹ́ nibẹ ṣalaye fun BBC Yoruba ni kikun lori odo adagun naa.

O ni awọn kan ti wọn ko sinu odo naa ko pada jade bẹẹ nigba ti wọn sọ okuta sinu odo adagun ọhun, ìlú jinjin si Oyo ni wọn ti lọ ri awọn nkan naa.