N16.39tn budget funding: Ààrẹ Buhari, ta ibùdó ìwapo látí wá owó fún ètò ìṣúná 2022- Àwọn onímọ̀

Aarẹ Buhari lasiko to n ba awọn ọmọ Ile Aṣofin sọrọ lori eto iṣuna naa ni awọn ṣetan lati ya owo to to triliọnu mẹfa naira lati fi ṣe eto iṣuna ọdun to n bọ naa.

O ni bi o tilẹ jẹpe lootọ ni ijọba ohun ti kọja gbendeke oye owo to yẹ ju awọn ya, amọ iṣe akanṣe ti awọn fẹ ṣe lo kan an ni ipa fun awọn lati ya owo.

Amọ o ni owo ẹya yii ko i tii kọja afarada nitori awọn n lo awọn owo yii daradara, paapaa lasiko ti ọrọ aje dẹnukọlẹ,

Ààrẹ Buhari, wá ọ̀nà míràn látí wá owó fún ètò ìṣúná 2022, ẹ̀yáwó ojojúmọ́ tí pọ̀jù- Ilé Ìgbimọ̀ Aṣòfin

Awọn onimọ nipa eto ọrọ aje ti rọ aarẹ Buhari lati ta awọn ibudo iwapo lorilẹede Naijiria ki owo le wa fun ijọba lati ṣe eto iṣuna ọdun 2022.

Eyi ko ṣẹyin iyanju ti Ile Igbimọ Aṣofin Agba gba ijọba apapọ pe ki wọn rọra lori ọrọ owo ẹyawo ojoojumọ.

Ọjọọbọ, Ọjọ Keje, Oṣu Kẹwaa, ọdun 2021 ni Aarẹ Buhari gbe aba iṣuna ọdun 2021 lọ si Ile Igbimọ Aṣofin to le ni triliọnu mẹrindinlogun Naira fun ọdun 2022.

Ati wi pe eleyii ti awọn fẹ ya naa ni wọn yoo lo lati fi pari awọn eto iṣẹ akanṣẹ ti awọn ti bẹrẹ.

Bakan naa ni aarẹ ni ki awọn ọmọ Naijiria fi ọkan balẹ lori ọrọ ẹyawo naa nitori awọn mọ ohun ti wọn n ṣe.

Aarẹ Buhari o to gẹ lori ẹyawo, o ti n pọju - Aarẹ Ile Igbimọ Aṣofin

Ninu ọrọ tirẹ, Aarẹ Ile Igbimọ Asofin Agba, Ahmed Lawan ti parọwa si aarẹ Buhari ati ijọba rẹ pe ki wọn ṣọ ara ṣe lori ọrọ ẹyawo ojoojumọ ni Naijiria.

Lawan ni idi ti awọn fi buwọlu owo ẹya ni igba naa ni pe o niiṣe pẹlu ọrọ pajawiri lori awọn iṣẹ akanṣẹ ti wọn n ṣe kaakiri orilẹede Naijiria.

O ni ijọba gbọdọ wa wọrọkọ fi ṣe ada lori ọrọ bi wọn ṣe le ma a pa owo wọle ni abẹle ni orilẹede Naijiria.

Aarẹ Ile naa ni ẹka iṣejọba ati ẹka aṣofin gbọdọ ṣiṣẹ papọ lati fi opin si ọrọ ẹyawo naa, ki owo si ma a wọle ni abẹlẹ.

''Buhari ta awọn ibudo iwapo to wa ni Naijiria ki owo le wọle ni abẹle ti wọn nilo lati ṣe eto iṣuna ọdun 2022''

Ọkan lara awọn onimọ to sọrọ naa,Nnaemeka Obiaraeri, ni ẹyawọ to to triliọnu mẹfa naira kọja afarada, nitori pe ọjọ ọla Naijiria ni yoo ṣe akoba fun un.

''Eleyii to yẹ ki ijọba Naijiria fi eto iṣuna mu idagbasoke ba ọrọ ajẹ Naijiria ki owo ni abẹlẹ gberu si, niiṣe ni ijọba n ya owo si.''

''Ijọba ni awọn ohun ini bii ibudo iwapo ti awọn alajẹbanu ninu ijọba n lo lati ko owo jẹ ti ko si ni ipa rere kankan ninu eto ọrọ aje Naijiria.''

''Ti ijọba ba ta awọn ohun ini yii, owo ti ijọba n na lori rẹ yoo kuro, ti wọn yoo si le lo ọwọ naa fun nkan miran.''