Eid-el-Kabir: Tinubu rọ àwọn mùsùlùmí láti tẹ̀lé ìlànà Allah bí wọ́n ṣé ń yayọ̀ ọdún

Eekan ẹgbẹ oṣelu APC, Asiwaju Bola Tinubu ti rọ awọn musulumi lati fi ara wọn jin, ki wọn si maa tẹle Ilana Allah bi wọn ṣe n ṣọdun Ileya.

Tinubu tun rọ àwọn musulumi lati maa gbagbe awọn alaini bi wọn ti n ṣe ọdun Sallah.

Aṣiwaju ni awọn musulumi ko gbọdọ gbagbe pe ohun ti ọdun Ileya wa fun ni lati ṣeranwọ fawọn ti ko rọwọ họri.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Tinubu sọrọ yii ninu atẹjade to fi sita lati ọwọ oludamọran rẹ lori eto iroyin, Tunde Rahman.

Tinubu sọ ninu atẹjade ọhun pe awọn iṣoro to n koju Naijiria nilo kawọn eeyan tubọ maa tẹle ofin Allah.

Aṣiwaju ni nipa bẹẹ ni orilẹ-ede Naijiria fi le bori awọn ipenija to n koju rẹ.

Tinubu tun rọ awọn musulumi lati rántí Aarẹ Muhammadu Buhari, awọn gomina at'awọn olori mii ninu adura bi wọn ṣe n ṣe ayẹyẹ ọdun Sallah.

Aṣiwaju ni awọn olori Naijiria nilo adura ki wọn le wa ojutuu s'awọn ìṣòro tó n ba orilẹ-ede yìí finra.

Gomina ipinlẹ Eko nigba kan ri ni bayii ni tonile talejo fi le jẹ anfaani orilẹ-ede Naijiria.

"Nitori naa, ninu ayẹyẹ ọdún Ileya yii, a gbọdọ wa oju Allah ki a sì gbé ounjẹ fawọn otosi.

A tun fi asiko yii gbadura fawọn ọmogun wa ati gbogbo awọn ẹṣọ eleto abo to n koju awọn janduku lojoojumọ.

A tun gbadura fun iṣọkan orilẹede Naijiria lasiko yii.

Mo ki gbogbo awọn musulumi ati gbogbo ọmọ Naijiria ku ọdun Ileya," Tinubu lo sọ bẹẹ.