Igboho, Yoruba Nation rally: A kò gbọ́ pé Sunday Igboho fẹ́ ṣe ìwọ́de ní ìpínlẹ̀ Eko- Kọmisọ́nnà ọlọ́pàá`

Gbajugbaja ajijagbara nilẹ Yoruba, Ọgbẹni Sunday Adeyemo, ti ọpọ eeyan mọ si Sunday Igboho kede pe oun yoo ṣe iwọde idasilẹ orilẹ-ede Oduduwa ni ipinlẹ Eko, lọjọ kẹta, oṣe Keje.

Amọ ileeṣẹ ọlọpaa ti sọ pe ko si ẹni to fi ọrọ iwọde naa to awọn leti.

Kọmisọnna ọlọpaa nipinlẹ naa, Hakeem Odumosu sọ fun iwe iroyin 'The Nation' pe oun ko gbọ pe iwọde kankan fẹ ẹ waye nipinlẹ Eko, nitori pe ẹnikẹni ko kọ iwe si ileeṣẹ ọlọpaa lati sọ fun wọn.

"Ti asiko ba to, ao mọ nkan ti ao ṣe nipa rẹ."

Ṣaaju ni gomina ipinlẹ Eko, Babajide Sanwo-Olu ti kede pe ipinlẹ naa ko lọwọ si ipolongo pe ki ẹya Yoruba pin kuro ni ara orilẹ-ede Naijiria.

Ninu ikede to fi sita ni ọjọ diẹ sẹyin, gbagede Freedom Park ti wọn fi sọri agba agbẹjọro, Oloogbe Gani Fawẹhinmi, eyi to wa ni agbegbe Ọjọta nipinlẹ Eko, ni Sunday Igboho sọ pe iwọde Yoruba Nation naa yoo ti waye.

Igboho ni "ko si ẹnikẹni to le sọ pe ki a ma wa si ipinlẹ Eko, nitori pe iwọde alaafia ni a fẹ sẹ. A ti ṣe ni Ogun, Ondo, Ekiti ati Osun.

Ati pe ere gbogbo di Freedom Park.