NIN SIM:Gbogbo ẹ̀yin tí 'SIM Card' yín tí sọ̀nú, ẹ wo ọ̀nà tí ẹ lè fi gbà á padà!

Ijọba orilẹede Naijiria ti fun awọn eniyan ni anfaani lati gba SIM Card won pada, eleyii to ti sọnu, amọ wọn gbọdọ ni nọmba idanimọ NIN.

Eleyii tun mọ si pe awọn ileeṣẹ ẹrọ ibanusọrọ bii MTN,GLO,9MOBILE,Airtel ti le fun awọn eniyan ni Sim tuntun lati fi rọpọ eleyii ti wọn ba sọnu bayii.

Osu Kejila, ọdun 2020 ni Ajọ to n risi eto ibanisọrọ lorilẹede Naijiria, National Communications Commission, NCC ti ni ki gbogbo awọn ileeṣẹ to n pese itakun fun ibanisọrọ lori foonu, dawọ tita kaadi ibanisọrọ duro.

Bakan naa lo ni ki wọn tun dẹkun eto iforukọsilẹ fawọn olubara to n ra kaadi pelebe inu foonu lati fi sọrọ duro ni kiakia.

Oludari ẹka ọrọ to kan araalu labẹ ajọ NCC, ọmọwe Ikechukwu Adinde, ni awọn pa aṣẹ yii ki ajọ naa baa le ṣe ayẹwo iwe owo iye awọn to n ra afẹfẹ ibanisọrọ lọwọ wọn.

Amọ, Ijọba yii ohun wọn pada lẹyin ti Minisita fun ọrọ ibanisọrọ, Isa Ibrahim Pantami jiroro lori igbeṣẹ naa.

Awọn ilana wa ti awọn ọmọ Naijiria gbọdọ tẹle lati le gba Sim Card wọn pada;

  • Ẹni to ba fẹ gba Sim Card rẹ pada gbọdọ ni nọmba idanimọ NIN
  • Ajọ iforukọsilẹ lorilẹede Naijiria, NIMC gbọdọ fi ontẹ lu nọmba idanimọ NIN naa
  • Bakan naa ni awọn ileeṣẹ ibanisọrọ yii gbọdọ tẹle ofin ijọba to rọ mọ iforukọsilẹ naa.