Pastor Adeboye: Kò sí ẹni tó sọ fún wa pé àjẹ́ ní COVID-19 àti pé òru ló n fò- Pasitọ Adeboye

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 6

Pasitọ igba Ijọ Redeem Christian Church of God, Enoch Adeboye ti bu ẹnu atẹ lu ijọba orilẹede Naijiria lori bi wọn ṣe fofin de isin irekọja si ọdun 2021.

Adeboye lo sọ bẹẹ lasiko to waasu ni isin Ọjọ Isinmi, Ọjọ Kẹta, Osu Kini, ọdun 2021 ni ile ijọsin rẹ.

O ni o ṣe ni laanu pe ijọba n kede fun awọn eniyan lati ṣe isin ọdun tuntun ni ago mẹwaa, aago mọkanla nigba ti o yẹ ki wọn rekoja si ọdun tuntun.

''Nitori naa ni a ṣe joko si ile wa, ti a si ṣe isin ni aago mejila, ti a fi rekọja si ọdun tuntun''

''Ko si ẹni to sọ fun wa pe, ajẹ ni Coronavirus to n fo loru, to si le e panijẹ ni oru, iyẹn aago mejila gan an.''

Bakan naa ni baba kesi awọn eniyan lati lọ si ile ounjẹ Buka lati lọ jẹun, ti ijọba ba kọ lati fun wọn laaye lati lọ si awọn ile ounjẹ igbalode.

Ọpọlọpọ awọn Naijiria ni wọn ti n fi esi fun ijọba lori ohun ti baba Adeboye sọ naa, ti o si n pa ọpọlọpọ eniyan lẹrin.

Alakoso agba fun ijọ RCCG, pasitọ Adejare Adeboye naa ti kede awọn asọtẹlẹ rẹ fun ọdun 2021.

  • O ni ọpọ isẹlẹ to waye lọdun 2021 to kọja naa la gbe lọ sinu ọdun tuntun
  • Fun abẹrẹ ajẹsara kọọkan ti wọn ba n se jade, orisi akọtun arun Coronavirus tuntun naa ni yoo tẹle
  • O ni eyi yoo si tẹsiwaju titi ti gbogbo agbaye yoo fi gba pe Ọlọrun nikan lo ni aabo lọdọ
  • Awọn ọmọ Naijiria to gbọ ohun lati ọrun, ti ọdun 2021 yoo si kun fun ọpọ ẹri rere nipa didara Ọlọrun
  • O wa rọ awọn Kristiẹni lati jẹ olotitọ ninu sinsin Ọlọrun, ki wọn si maa tẹle Jesu Kristi, ki ẹnu wọn le kun fun ọpẹ nipa rere Oluwa.

Ti Aarẹ Muhammadu Buhari ko ba mura, ẹsẹ ijọba rẹ lọdun 2021 yii.

Alufa ijọ Aguda to tun jẹ oludari ijọ Adoration Ministries niluu Enugu, Rev Fr Ejike Mbaka lo sọ asọtẹlẹ yii.

Alufaa Mbaka ṣalaye pe bo ya ijọba Buhari yoo wa sopin tabi ko ni wa sopin da lori bi Buhari ba ti yara ṣiṣẹ si.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Ninu ọrọ rẹ, Mbaka gba ijọ apapọ ni imọran lati pese iṣẹ fawọn ọdọ ni Naijiria lati le dẹkun iwa jagidijagan tawọn ọdọ tun le gunle.

O ni bi bẹẹ kọ, iwa ipa awọn ọdọ le da oju ijọba Buhari bolẹ.

Alufaa Mbaka ko ṣai sọrọ sawọn ọmọ ile igbimọ aṣofin agba l'Abuja lẹyin to ṣapejuwe wọn gẹgẹ bi ajinigbe.

''Ibinu Ọlọrun n bọ lori gbogbo ọpọ awọn oloṣelu to ti kowo ijọba jẹ,'' Mbaka lo sọ bẹẹ.

Bakan naa lo tun sọ pe ibinu Ọlọrun tun wa lori awọn olori orilẹede Naijiria nigba kan ri atawọn to wa lori aleefa lọwọ nitori wọn ti sọ awọn ọdọ di atọrọjẹ lawọn orilẹede mii.

Mbaka kilọ fawọn eeyan lati maa kọ eti ikun sawọn asọtẹlẹ oun bi bẹẹ kọ, asọtẹlẹ naa le ṣẹ mọ wọn lori.

Ìjọ Mountain of Fire fi àwọn àsọtẹ́lẹ̀ ìbẹ̀ru sítà fuń ọdun 2021

Ijọ Mountain of Fire ti fi awọn asọtẹlẹ jade fun ọdun 2021 sita, bii awọn ojisẹ Ọlọrun miran ṣe n sọtẹlẹ nipa awọn isẹlẹ ti yoo waye lọdun tuntun 2021 ati bi ọdun naa yoo se ri.

Oludasilẹ Ijọ MFM, Daniel Olukoya pe akọle awọn asọtẹlẹ naa ni 'Year of Restoration and Revival', lasiko isin ọdun tuntun ninu ile ijọsin rẹ.

Olukoya wa rọ awọn ọmọ Naijiria lati ma a gba adura, ki wọn si kun fun nitori ohun gbogbo ti wọn n fẹ ni yoo tẹ wọn lọwọ ti wọn ba gbadura.

''Adura kikankikan ni wọn nilo lati koju arun Coronavirus ti gbongbo, ti gbongbo.''

''Ọpọlọpọ ẹkun ohun ipayinkeke yoo pọ ninu ọdun tuntun naa, nitori naa ni adura ṣe ṣe koko''

''Ọpọlọpọ idojukọ ati idunkoko mọni ni yoo waye ninu ọdun tuntun naa.''

''Ti a ko ba gbadura kikan-kikan, esu yoo gbogun ti orilẹede naa, ti ifẹhọnuhan ohun ija yoo si gbode kan.''

''Baamu Gilead nikan lo le gba awọn eniyan la lọwọ ipayinkeke ati iditẹmọni ti yoo waye ninu ọdun 2021 naa''

Bakan naa ni o ni ki awọn eniyan gbadura kikan ki omiyale agbara ya sọọbu ati awọn iṣelẹ pajawiri layika, ko ma gba ọdun naa jẹ mọ awọn eniyan lọwọ.

Wo ọ̀pọ̀ àsọtẹ́lẹ̀ táwọn òjíṣẹ́ Ọlọ́run sọ nípa ọdún 2021

Ọpọ eeyan lo n fapa janu pe ọdun 2020 to kọja lọ ko dara to, ti wọn si n foju sọna si awọn ohun rere tabi isẹlẹ ti yoo waye lọdun 2021, eyi ti yoo jẹ ki wsn gbaradi de ọdun tuntun naa.

Bi o tilẹ jẹ pe lara awọn asọtẹlẹ tawọn ojisẹ Ọlọrun naa sọ lọdun 2020 ko wa si imusẹ, sibẹ, ọpọ wsn tun ti jade bayii lati sọ ohun ti ẹmi sọ fun wsn pe yoo waye ninu ọdun 2021.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Awọn ojisẹ Ọlọrun to ti sọ asọtẹlẹ tiwọn jade fun ọdun 2021 ree:

Primate Elijah Babatunde Ayodele: Ẹ gbadura, ọdun 2021 yoo le ju 2020 lọ

Odu ni wolii Ayodele ni agbo awọn ojisẹ Ọlọrun, kii si se aimọ fun oloko lagbo awọn ọmọlẹyin Kristi pẹlu.

Koda,aimọye asọtẹlẹ lo ti sọ lati aimọye ọdun sẹyin, tawọn kan ninu wọn si wa si imusẹ nigba ti awọn miran kuna lati sẹ.

Ojisẹ Ọlọrun yii, tii se oludasilẹ ijọ INRI Evangelical, ninu asọtẹlẹ fọdun 2021 ti wa kede pe awọn nnkan wọnyi yoo waye:

  • Ọdun 2021 yoo le pupọ ju ọdun 2020 to rekọja lọ, to si rọ awọn ọmọ Naijiria lati gbadura daradara
  • Abẹrẹ ajẹsara fun idena Coronavirus yoo sisẹ lara awọn eeyan amọ arun naa yoo tubọ tan kalẹ pupọ, eyi ti yoo mu ki ijọba tun kede igbele miran
  • Osu Kẹsan ọdun 2021 ni ọwọja arun naa yoo to wa silẹ.

Enoch Adejare Adeboye: Abẹrẹ ajẹsara kọọkan to ba jade, akọtun arun Coronavirus tuntun ni yoo tẹle

T B Joshua: Mo sẹsẹ ti ori oke de ni, nibiti Ọlọrun ti fi asọtẹlẹ nipa 2021 han mi, yoo jade laipẹ

Oludasilẹ ijọ Tabernacule naa, T B Joshua ko ti fi ọrọ asọtẹlẹ kan sita dabi alara fun ọdun tuntun 2021.

  • Amọ Joshua ni Oluwa pa lasẹ fun oun lati gbe omi iyasimimọ ati iwe alẹmọ nnkan taa ms si Sticker sita, tawọn eeyan yoo maa lo lati daabo bo ara wọn
  • O ni oun sẹsẹ ti ori oke de ni, nibi ti Ọlọrun ti fun oun ni asọtẹlẹ nipa aọn ohun ti yoo sẹlẹ ninu ọdun 2021, eyi ti oun yoo gbe sita laipẹ
  • O ni ọpọ nnkan ti arun Coronavirus ti bajẹ lọdun 2020 ni yoo di atunse ni 2021.

Bisọọbu David Oyedepo: Esu n lo arun Coronavirus lati dide kọlu ijọ Ọlọrun ni

Awọn adura to dabi asọtẹlẹ ni Bisọọbu David Oyedepo, ti ijọ Winners Chapel gbe sita nipa ọdun 2021, lara awọn adura naa si ree:

Ọpọ isẹlẹ iyalẹnu ni yoo waye ninu ọdun 2021

  • Bẹrẹ lati ọdun 2021 lọ, a ko ni rin gberegbere kiri mọ ninu aye, bẹẹ ni a ko ni ri ijakulẹ rara
  • Iyipada wa yoo de lọdun 2021
  • Ipọnju ti aye mọ pẹlu wa ko ni ba wa wọnu ọdun 2021
  • Oyedepo, ẹni to pe akori iwaasu rẹ ni isin aisun ọdun ni 'A wa loju ọna lọ si ilẹ ileri wa' tun fikun pe esu n lo arun Coronavirus lati dide kslu ijọ Ọlọrun ni
  • Ojisẹ Ọlọrun naa ni ko si isin ori ayelujara to daa to lati fi rọpo isin ojukoroju nile ijọsin
  • O wa fikun pe "Ẹyin ara lọkunrin ati lobinrin, ko si ohun to n jẹ arun Coronavirus rara, koda, ọkan lara awọn gomina nilẹ Naijiria gan ni eeyan matrun pere lo ni arun naa nipinlẹ oun, nibo wa ni ariwo naa ti bẹrẹ
  • Eyi si lo mu ko maa beere pe ni arun Coronavirus wa?'

Nibayii ti ọdun ti wa wọle de, o dabi ẹni pe awọn ojisẹ Ọlọrun naa n sọra se lati sọ asọtẹlẹ nipa ohun ti yoo waye lọdun 2021.

Idi ni pe ọpọ eeyan lo n tabuku awọn ojisẹ Ọlọrun naa pe ọpọ awọn asọtẹlẹ ti wọn kede lọdun 2020 ni ko wa si imusẹ.