Bea Lewis: Ọ̀rọ̀ Dangote lu Twitter pa lẹ́yìn tí ọmọbìnrin rẹ̀ nílẹ̀ Amẹrika sọ̀rọ̀ sókè

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 2

Gbajugbaja oniṣowo ọmọ Naijiria, Aliko Dangote ni ẹnin akọkọ tawọn eeyan yoo maa sọ nipa rẹ lori ayelujara lẹyin ti ọmọbinrin ilẹ Amẹrika kan, Bea Lewis sọ pe awọn ti fẹ ra ri.

Lọjọ ọdun, ọjọ kinni oṣu kinni ọdun 2021 ni Lewis to jẹ oniṣowo niluu Atlanta l'Amẹrika fi si oju opo Instagram rẹ pe oun ti jẹ ọrẹbinrin ọkunrin ilẹ Afirika to lowo julọ lagbaaye.

Amọ Lewis sọ ninu ọrọ to fi lede loju opo Instagram rẹ pe Dangote ja oun kulẹ lori ọrọ ifẹ to wa laarin wọn.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Boya awọn eeyan ko ba ti ka ọrọ arabinrin naa kun ṣugbọn niṣe lo fi fọto tawọn mejeeji jọ ya soju opo Instagram rẹ.

Fọto yii atawọn mii gan an lo jẹ ki awọn ọmọ Naijiria bẹrẹ si ni gba ọrọ naa bi ẹni n gba igba ọti lori ayelujara, papaa julọ loju opo Twitter.

Bi awọn eeyan ṣe n sọ oriṣiiriṣii lori ọrọ naa, Dangote ko tii fesi kan, ko si ye ẹnikan bo ya lootọọ ni Lewis fẹ baba olowo naa ri.

Lewis ko ṣai ki Dangote fun ọpọ ẹkọ ti oun ri kọ lara rẹ nigba ti awọn fi n fẹ ara awọn.

O ni Dangote loun ri ẹkọ kọ lara rẹ julọ ninu gbogbo eeyan ti oun ti ba pade laye.

''Biba olowo bi Dangote sọrọ lojoojumọ yoo jẹ ki eeyan ni oye to yatọ nipa aye,'' Lewis lo woye bẹẹ.

Ero awọn ọmọ Naijiria ṣọtọọtọ lori ayelujara lori ọrọ Lewis ati Dangote.

Bi awọn kan ṣe n fi ọrọ naa ṣe ẹfẹ lawọn kan gbe ọrọ naa ka ori.

Ta ni Bea Lewis gan an?

Gẹgẹ bi ohun to kọ si oju opo LinkedIn rẹ, Lewis kẹkọọ ninu imọ ọrọ aje ati ẹkọ imoye ni fasiti ipinlẹ Georgia lorilẹede Amẹrika.

A ko le sọ bo ya o jade nile iwe naa lọdun 2012 tabi 2013.

Ilumọọka ni Lewis niluu Atlanta nitori ibi to ti n ta ounje fawọn eeyan lalaalẹ.

Oun ni oludasilẹ ileeṣẹ ounjẹ kan ti orukọ n jẹ Atlanta Meal Prep.

Lewis tun sọ loju opo Twitter rẹ pe oun ni ọmọdebinrin kan.

Bakan naa lo tun sọ nipa ọkọ rẹ ninu ọrọ mii to fi lede loju opo Twitter rẹ.

Lakotan, Lewis mọ nipa ọti waini daadaa, koda o maa n ta ọti waini.