Alaafin Oyo: Bá wo ni òrékelẹ́wà Adedoja tó gbàmì ẹ̀yẹ ''Miss Oyo 2020'' ṣe jẹ́ sí Alaafin?

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 1

Ọpọ lo mọ oniruuru arẹwa mọ Oba Lamidi Olayiwola Adeyemi, Alaafin Oyo.

Amọ, bi awọn arẹwa Olori ṣe rọgba yi Iku Baba ka naa ni Eleduwa fi awọn ọmọ to rẹwa ta baba lọrẹ.

Laipẹ yii ni Ọmọbabinrin Adedoja Adeyemi gba ami ẹyẹ arinrin oge gẹgẹ bi ọdọbinrin to rẹwa julọ nipinlẹ Oyo.

Adedoja, ẹni ọdun mẹrinlelogun gba la awọn oludije mii ti wa lati ẹkun mẹrinla ipinlẹ mọlẹ lati gba ami ẹyẹ naa.

Ọmọbabinrin Adedoja gba ẹbun ọkọ ayọkẹlẹ Toyota Camry lọ ile atawọn ẹbun miiran.

Adedoja to kẹkọọ gboye nipa itan nile iwe fsaiti ipinlẹ Oṣun, UNIOSUN ti lọ si aafin Oyo fun adura lati ẹnu baba lẹyin to pegede tan nibi idije to ti kopa.

Ọmọbabinrin Adedoja n kẹkọọ lọwọ bayii lati gboye ẹkeji ni fasiti ilu Eko, UNILAG lori ilẹ Afirika.

Oun ni oludari ẹgbẹ kan to n ṣeranwọ fawọn ọmọ to ba ni arun foni ku fọla n de tawọn oloyinbo maa n pe ni SS.