Obasanjo ń jowú àṣeyọrí Buhari lọ ṣe ń kọ ìkọkúkọ nípa rẹ̀ - Iléeṣẹ́ ààrẹ

Iléeṣẹ́ ààrẹ Nàìjíríà ti fún ààrẹ tẹ́lẹ̀ rí Olusegun Obasanjo lésì lórí bó ṣe sọ wí pé ìṣèjọba ààrẹ Muhammadu Buhari gbóná janjan fún àwọn ọmọ orílẹ̀ èdè yìí.

Nínú àtẹ̀jáde kan tí agbẹnusọ Ààrẹ, Mallam Garba Shehu fi sórí Twitter rẹ̀ ní Obasanjo ń jowú ààrẹ Buhari nítorí tí ààrẹ Buhari ti ní àṣeyọrí ju ohun tí Obasanjo ṣe lọ nígbà tó wà nípò gẹ́gẹ́ bí ààrẹ.

Garba Shehu ní ìgbà àkọ́kọ́ kọ́ rè é tí Obasanjo yóò máa sọ̀rọ̀ òdì tàbí ju ọ̀rọ̀ ìkọlù sí ààrẹ Buhari nítorí gbogbo ọ̀nà ni ìjọba tó wà lóde fi kọjá ìdàgbàsókè tí ìjọba àwọn méjéèjì mú bá orílẹ̀ èdè yìí.

Nínú àtẹ̀jáde náà ni Shehu ti fẹ̀sùn kan Obasanjo pé nígbà tó ń wá sáà kejì gẹ́gẹ́ bí ààrẹ Nàìjíríà ló parọ́ fún àwọn ènìyàn ẹkùn ìlà-oòrùn gúúsù Nàìjíríà.

Ó fi kun pé bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ààrẹ Buhari kò rí ìbò kankan láti ẹkùn náà, ó ṣe afárá kejì Niger fún wọn.

Ó tẹ̀síwájú pé Obasanjo máa ń rò wí pé òun ni olórí tó dára jùlọ tí Nàìjíríà lè ní àmọ́ ó yà á lẹ́nu pé Buhari kọjá gbogbo nǹkan tí òun ṣe.

Shehu ní Obasanjo tún parọ́ pé òun máa ri dájú pé òun ṣètò ìdìbò tó gbé oúnjẹ fẹ́gbẹ́ gba àwo bọ̀ ṣùgbọ́n kò rí bẹ́ẹ̀ nígbà tí yóò fi kúrò nípò.

Ó ní ìdí nìyí tí Obasanjo fi ń rán oró nípa gbogbo àwọn nǹkan tó ń kọ láti fi tàbùkù ààrẹ Buhari.

Olóṣèlú tó ti tán fún ni Obasanjo, kò lè gbé Peter Obi wọlé - Tinubu

Igbimọ oludari ipolongo ibo aarẹ fún ẹgbẹ́ oṣelu All Progressives Congress (APC) ti ṣàpèjúwe atilẹyin Olusegun Obasanjo fun Peter Obi, gẹgẹ bi nkan ti ko já mọ́ nkankan.

Ọjọ kinni, oṣu Kínní, ọdun 2023, ni Obasanjo sọ ninu lẹta kan to kọ si awọn ọmọ Naijiria pe, olúdíje sipo aarẹ ninu ẹgbẹ́ Labour, Peter Obi ni oun fọwọ sí.

Sugbọn ninu atẹjade kan, oludari ìkéde ati iroyin ninu ìgbìmọ̀ ìpolongo ibo fun Bola Ahmed Tinubu ati igbakeji rẹ, Kashim Shettima,

Bayo Onanuga sọ pe nkan ti Obasanjo sọ ko dẹruba wọn rárá.

Bayo Onanuga sọ pe ọjọ ti pẹ ti Obasanjo ti ma n tako ẹgbẹ́ onitẹsiwaju, gẹgẹ bo ṣe ṣe fun olóògbé MKO Abiola lọdun 1993.

"Fífi ọwọ si Peter Obi, ko jamọ nkankan nitori pe aarẹ nigba kan ri ọhun ko ni agbara oṣelu kankan lati gbe ẹnikẹni de ipo kánsélọ̀ adugbo to kere ju, debi ipo aarẹ.

" Àkọsílẹ̀ wa fihan pe Obasanjo kò ri ẹnikẹni gbé de ipo, lati ọdun igba to ti kuro nipo."

Ọgbẹni Onanuga sọ pe nkan to da awọn loju ni pe Peter Obi ko le bori ni ibudo idibo Obasanjo fúnra rẹ n'ilu Abeokuta "nítorí pe oloselu to ti tán fun ni.

Ọ̀dó ní ipò ààrẹ́ kàn ní ọdún 2023 kìí ṣe àgbàlagbà – Oluṣegun Obasanjọ

Aarẹ tẹlẹri lorilẹede Naijiria, Oluṣẹgun Obasanjọ ti buwọlu oludije sipo aarẹ ni ẹgbẹ oṣelu Labour Party, Peter Obi.

Obasanjo n fi ero rẹ ni ayajọ ọdun tuntun saaju idibo sipo aarẹ lorilẹede Naijiria ti yoo waye ni Osu Keji, ọdun 2023.

Ninu lẹta to kọ si awọn ọmọ Naijiria fun ọdun tuntun lo ti di ero rẹ han ati adura fun ọdun tuntun naa.

Peter Obi pegede ninu awọn oludije si ipo aarẹ ni ọdun 2023 - Obasanjọ

Ninu lẹta naa ni Obasanjo ti sapejuwe gbogbo awọn to n dije du ipo aarẹ lorilẹede Naijiria gẹgẹ bi awọn ti oun jẹ Baba fun.

O ni gbogbo wọn ni wọn n wo awokọṣe oun nigba ti oun di ipo aarẹ mu ni Naijiria.

Amọ o ni igba ti yipada ti awọn ọdọ si gbọdọ dide lati di ipo adari mu ni Naijiria , ki igba le yipada.

‘’Ko si ẹni ti ko ni abawọn ninu awọn oludije sipo aarẹ ni Naijiria amọ lati yan adari a gbọdọ wo iṣe ti wọn ti ṣe si ẹyin ati iwa wọn.’’

Nibayii, a nilo ẹni ti yoo di ipo adari mu lai wo ẹyin, ti yoo si sa gbogbo ipa rẹ’’

‘’Pẹlu gbogbo eleyii, ero mi ni pe Peter Obi lamilaaka ju gbogbo awọn oludije to ju lọ to fi mọ igbakeji rẹ’’

‘’Ohun miran nipa Peter Obi ni wi pe ọmọ lo jẹ si wa, ti a si le bawi ti o ba ṣe ohun ti ko tọ, ti yoo si gbọ si wa lẹnu.’’