Adeboye, Ayodele, Enenche sọ àṣọtẹ́lẹ̀ fún 2023

Pasitọ agba ijọ Redeem, Enoch Adeboye ti sọ asọtẹlẹ pe alaafia to pọ yoo jọba ni ọdun 2023.

Adeboye to sọ ọrọ naa nibi eto isin irekọja si ọdun 2023 sọ pe ọpọlọpọ awọn to fẹran lati ma a da wahala silẹ, yoo padanu agbara wọn lati ṣe bẹẹ.

Bakan naa lo sọ pe ayipada oju ọjọ yoo lagbara gan-an, amọ ko nii buru ju nibi ti awọn ọmọ Ọlọrun ba wa.

“Alaafia yoo jọba si l’agbaye.

“Ọpọlọpọ awọn to n da wahala silẹ ni yoo sọ agbara wọn nu, ti wọn o si ni le ṣe bẹẹ mọ.

Kini Primate Ayodele so nipa 2023?

Bakan naa, ni oludasilẹ ijọ Inri Evangelical Spiritual Church nipinlẹ Eko, Primate Elijah Ayodele, ti kilọ pe eto ọrọ aje yoo buru si ni Naijiria, ati awọn orilẹ-ede agbaye lọdun 2023.

Ninu ọrọ ọdun tuntun to sọ, Ayodele sọ pe ijọba apapọ yoo tun fi kun owo ori, ti ọpọ gomina ko si ni rowo san owo oṣu awọn oṣiṣẹ rẹ.

O ni ọkan pataki lara awọn oludije si ipo aarẹ lọdun 2023, yoo ba ijakulẹ pade, nitori pe awọn to sun mọ yoo dalẹ rẹ, ti awọn oludije kan yoo si ku ṣaaju ọjọ idibo, ti awọn ilumọọka mii naa yoo si ku.

Kini Pasito Paul Enenche sọ?

Ninu ọrọ ọdun to sọ naa, pasitọ agba ijọ Dunamis International, Paul Enenche ti sọ asọtẹlẹ pe ayipada ọtun yoo ba Naijiria lọdun 2023.

Enenche to sọrọ naa nile ijọsin rẹ nibi aisun ọdun sọ pe imọlẹ ti de si Naijiria lọdun 2023.