Ẹ máa ṣe àmín bí Adewale Alebiosu, àgbà òṣèré tíátà, ṣe ń gbàdúrà ọdún túntún fún yín

Ẹ máa ṣe àmín bí Adewale Alebiosu, àgbà òṣèré tíátà, ṣe ń gbàdúrà ọdún túntún fún yín

Adewale Alebiosu: Gbogbo wa lá pésẹ̀ ní àmọ́dún, ọdún ayọ̀ lá ṣe

Yoruba ni adura nii gba, agbara kọ, ohunkohun ta ba si fi le adura, o maa n ja si rere ni.

Nibayi ti ọdun 2022 yoo wa sopin lonii, adura ni ọpọ eeyan yoo fi kalẹ rẹ nilẹ, ti wọn yoo si tun se isọ osu lati ki ọdun tuntun 2023 kaabọ

Adura opin ọdun yii ko yọ ẹnikẹni silẹ, nitori bawọn Kristiẹni se n lọ se isọ oru, naa lawọn Musulumi yoo maa se Tajud ninu ile tabi ni ipejọpọ kan.

Bakan naa si lawọ̀n ẹlẹsin ibilẹ yoo maa se aisun lati rawọ ra ẹsẹ si Eledumare.

Idi ree ti BBC Yoruba fi tọ agba ọjẹ osere tiata ati onisẹse lọ lati lọ wa se adura nla fun ẹyin ololufẹ BBC Yoruba.

O ya, ẹ wa se adura witi-witi, bi Adewale Alebiosu se n se adura ọdun tuntun fun yin.

A ku ọdun, aseyi samọdun, ọdun yoo yabo fun gbogbo wa.