You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Ènìyàn mẹ́jọ̀ sọ ẹ̀mí rẹ̀ nù nínú ìjàmbá ọkọ̀ ní ọdún tuntun
Ọpọlọpọ ijamba ọkọ lo waye ni ọjọ kini ọdun tuntun 2023 ti a ṣẹṣẹ wọ.
Awọn iṣẹlẹ yii waye ni popona moroṣe ibadan si Eko ati opopona Sagamu si Benin ni ọjọ kan naa.
Awọn to farapa ninu ọkọ ayokele ati ọkọ nla wa ni ileewosan nibi ti wọn ti n gba itọju.
Eniyan meje ku, mẹrindinlogun farapa ni ijamba ọkọ to waye ni opopona marosẹ Eko si Ibadan
O kere tan eniyan meje ni wọn ti fidi rẹ mulẹ pe wọn ku ni ọjọ Isinmi, Ọjọ Kini, osu Kini, ọdun 2023.
Kọ Toyota Hiace ati ọkọ agbepo ni wọn kọju ara wọn ni agbegbe Gofamint.
Adari ikọ FRSC ni ipinlẹ Ogun, Ahmed Umar fi idi iṣẹlẹ naa mulẹ fun awọn oniroyin ni Abeokuta
Umar ni iṣẹlẹ naa waye ni nkan bi aago mẹrin to si ni iwakuwa loju popo lo fa iṣẹlẹ naa.
O ni awakọ igboro naa n sare asapajude nigba to lọ lọjju tirela lati ẹyin.
Eniyan kan ku ni ijamba ọkọ opopona Sagamu si Benin
O kere tan eniyan kan gbẹmi mi ni ijamba ọkọ to waye laarin ọkọ Toyota Sienna kan ati ọkọ Toyota Rav4.
Iṣẹlẹ naa waye ni agbegbe Remo Majestic Hotel ni Sagamu, ni opopona marọṣẹ Sagamu- Benin.
Agbẹnusọ fun ikọ oju popo ni ipinlẹ Ogun, Babatunde Akinbiyi fi idi iṣẹlẹ naa mulẹ fun awọn oniroyin ni ilu Abeokuta.
Akinbiyi salaye pe iṣẹlẹ naa waye ni aarọ ọjọ isinmi lẹyin ti taya ọkọ fọnka to si lọ forisọ ọkọ miran.
O salaye pe eniyan meje ni o farapa ninu iṣẹlẹ naa.
Bakan naa lo wa gba awọn awakọ ni imọran lati ṣọra fun sisa ere asapajude.