Kí ló dé táwọn àgbẹ̀ ń sùn sóko láti dá ààbò bo nǹkan ọ̀gbìn wọn?

Aworan awọn Agbẹ

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 2

Lorilẹede Naijiria lọwọ yii, ibẹrubojo ni ọpọ awọn agbẹ fi n ṣiṣẹ wọn, ti pupọ wọn si ni lati sun sinu oko lati le da abo bo awọn nnkan ọgbin wọn lọwọ awọn ole.

Nipinlẹ Yobe ni apa ariwa orilẹede Naijiria, ọpọ agbẹ lo n la ọpọ wahala kọja ti pupọ si pinnu lati ma sun ninu oko wọn paapa ni alẹ mọju nitori bi awọn eeyan se gbero lati ka gbogbo nnkan ọgbin ti ọnse wahala lori.

Yatọ si awọn eeyan, ọpọ awọn ẹranko bi ọniv naa ja awọn agbẹ naa lole.

Awọn ijọba ibilẹ ti ọpọ iṣẹlẹ yii ti n waye ni ijọba ibilẹ Gujiba, Damaturu, Gashuwa ati awọn mii to sumọ.

Awọn agbẹ mii ni lati gba asọle lati ma sọ oko lasiko ti wọn ba si ni ibẹ nitori awọn eeyan ole ati ẹranko.

A ni lati mu ọkan ninu ka sun tabi ki a padanu nnkan oko wa

Malam Zakari Adamu fidi iṣẹlẹ yii mulẹ fun BBC, to si ni oun naa jẹ ọkan ninu awọn agbẹ to ti padanu ọpọ nnkan sọwọ awọn ole yii.

“Lati isin yii bayii, a ni lati lọ sinu oko, ki a lo mojuto ni alẹ, ati ọsan ati alẹ a n fi wa loko.

“Bi awọn nnkan ba ti to ka, ni a ni lati wa ninu oko wa, bi bẹ kọ, ọpọ nnkan lo le waye.”

Malam Zakariya fikun pe awọn ole yii n ji nnkan oko mi iṣu ati agbado.

“Ẹ mọ pe asiko iṣu ni wa, ti a ko ba jafiya, awọn ople yii yoo palẹmọ nnkan oko wa.”

Malam Umar Matazu ni lati igba ti oun ti n dako, oun ko ri iru nnkan to n sẹlẹ yii ri.

“Bi mo se n ba yin sọrọ yii, ẹwa mi ti n tobi sugbọn ko ti to asiko lati ka kuro sugbọn nitori awọn ole, mo ni lati ka wọn kuro.