Òní ni àyájó ojó ìsèjoba tiwantiwa ní Naijiria

June 12 democracy Day: Òní ni àyájó ojó ìsèjoba tiwantiwa ní Naijiria

Aworan Buhari

Oríṣun àwòrán, Google

Ni orilẹede Naijiria, Ọjọ Kejila, Oṣu Kẹfa ni ọdọọdun ni wọn maa n ṣe Ayajọ ọjọ ominira ni Naijiria.

Eyi yipada kuro ni Ọjọ Kọkandinlọgbọn, Oṣu Karun un, ọdọọdun lẹyin aṣẹ Aarẹ Muhammadu Buhari ni ọdun to kọja.

Ni ọdun yii, Ayajọ ọjọ ominira naa n waye lasiko ti awọn ẹgbẹ oṣelu ni Naijria n mu idibo abẹle wa sopin ṣaaju idibo gbogboogbo ti ọdun to n bọ.

Ọjọgbọn Abubakar Mu'azu to jẹ onimọ nipa eto iroyin ni fasiti Maiduguri to ba BBC Hausa sọrọ ni ọjọ naa ṣe pataki ninu itan Naijiria nitori o tọkasi iya ti awọn eniyan jẹ lati gba ominira lọwọ iṣejọba lọwọ awọn ologun.

O ni ọjọ naa n jẹ ki awọn ọmọ Naijiria mọ bi wọn ṣe ja fitafita, ti awọn kan si lọ si ẹwọn lati le gba iṣejọba tiwantiwa pada.

Ọjọgbọn naa ni awọn miran tilẹ ṣakuro ni Naijiria lasiko ija fun iṣejọba tiwantiwa.

‘’Bio tilẹ jẹ pe wọn n ṣe ayajọ ọjọ naa, inu awọn eniyan ko dun nitori wọn ro pe ijọba tiwantiwa yoo mu igbayegbadun, alaafia ati idagbasoke ba orilẹede Naijiri.

Amọ nkan ko fi ara rọ, ti awọn miran tilẹ n sọ pe kini anfaani iṣejọba tiwantiwa lai si alaafia ni ilu.

Mọ si nipa June 12…

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Ayajọ ọjọ naa jẹ manigbagbe ti awọn ọmọ Naijiria dibo ni ọdun 1993 lati yan aarẹ tuntun, amọ ajọ eleto idibo ko kede ẹni to jawe olubori.

Amọ gbogbo eniyan lo n tọka sipe oludije lẹgbẹ oṣelu SDP, Moshood Kashimawo Olawale Abiola lo jawe olubori, ti ẹni ti wọn jọ figagbaga Bashir Othman ti ẹgbẹ oṣelu NRC si fidirẹmi.

Esi idibo naa ni wọn dabaru rẹ lẹyin ti ijọba Ologun labẹ Ibrahim Babangida paṣẹ ki wọn fi ọwọ osi daanu.

Eyi lo da wahala silẹ ti wọn si bẹrẹ fun ijọba tiwantiwa, amọ niiṣe ni wọn bẹrẹ si ni ti wọn mọ ilẹ kaakiri to fi mọ Abiola.

Ayajọ June 12 naa tunbọ fidimulẹ si gẹgẹ bi ayajọ ọjọ ominira nitori ni ọdun 1999 kan naa ni iṣejọba tiwantiwa bẹrẹ, ti wọn si ti n ṣayajọ ọjọ naa ni May 29, ki Buhari to yipada si June 12.

Amọ ijọba ipinlẹ Ondo ti kede pe awọn ko ni ṣe ayajọ June 12 lọdun yii nitori ikọlu ti awọn agbesunmọmi ṣe si ṣọọṣi ni Ọjọ Pentecost, ti wọn si pa eniyan ogoji.