'Wọn ti gba ìṣèjọba mọ́ Ààrẹ Buhari lọ́wọ́'

Aworan Babachir Lawal ati Aarẹ Muhammadu Buhari

Oríṣun àwòrán, Other/twitter/@MBuhari

Akọwe ijọba apapọ orilẹede Naijiria nigbakan ri, Babachir Lawal ti sọ pe awọn kan ti ja aṣẹ ijọba gba mọ Aarẹ Buhari lọwọ, ohun to wu wọn ni wọn si n ṣe lorukọ aarẹ.

Babachir Lawal sọrọ yii lasiko to fi n dahun ibeere lori eto kan lori ileeṣẹ mohunmaworan Channels lorilẹede Naijiria.

O ni gbogbo nnkan to n ṣẹlẹ lọwọ bayii fihan pe nnkan ko si ni ọwọ Aarẹ Buhari mọ.

Gẹgẹbi ọrọ rẹ, o han gbangba bayii pe awọn to sunmọ aarẹ n kọ lati tẹle aṣẹ rẹ.

Ko si nnkan to n jẹ “cabal” gbogbo ijọba lo n ni awọn alagbara ikọkọ

Babachir lawal

Oríṣun àwòrán, screenshot

Babachir Lawal to jẹ akọwe ijọba nigba ti aarẹ Buhari kọkọ de ori alefa sọ pe lootọ ni awọn kan maa n wa ninu iṣejọba to n sunmọ aarẹ ju awọn kan lọ, awọn wọnyi a maa ni agbara ni sakani wọn ju ọpọ miran ninu iṣe jọba.

O ni Awọn kan maa n pe awọn wọnyii ni alagbara ikọkọ ninu ijọba pẹlu adape “cabal” lede oyinbo, ṣugbọn gẹgẹbi ọr rẹ ko si ijọba naa lagbaye ti iru wọn kii si.

“Nnkan ti kuro lọwọ rẹ, ki a maa tan ara wa jẹ, awọn eeyan kan wa ti wọn kii tẹle aṣẹ ti aarẹb a pa fun wọn.

Ni kete ti wọn ba ti gba aṣẹ lati ṣe nnkankan, bi wọn ba ti ysẹ pada, ti inu wọn ni wọn maa ṣe. Ko si nnkan to n jẹ igbimọ alagbara ninu ijọba iyẹn ‘cabal. Ko si ijọba ti kii ni awọn ọmọ igbimọ abẹnu. Ko si ijọba.”

‘Okunkun ni PDP ati APC to wa nilẹ tẹlẹ, Peter Obi ni imọlẹ lo jẹ ki n sa tẹle lẹyin’

Nigba to n ṣalaye idi to fi fi ẹgbẹ oṣelu APC silẹ lọdarapọ mọ Labour Party, Babachir Lawal ṣalaye pe oun rii pe Peter Obi ni ‘imọlẹ’ lo jẹ ki oun lọdarapọ mọọ fun eto idibo apapọ ọjọ karundinlọgbọn oṣu keji.

O ni ekuru atijọ ni ẹgbẹ oṣelu APC ati PDP, okunokun ni wọn si duro fun. Lawal ni oun ti ri imọlẹ lo jẹ ki oun fi ẹgbẹ to wa ni ijọba silẹ.

“Mo ti ri imọlẹ, o lee ronupiwada ni kete ti o ba ti ri imọlẹ. Mo ri imọlẹ, mo si ronupiwada. Peter Obi ni imọlẹ naa; okunkun si ni awn ẹgbẹ to ti wa nilẹ tẹlẹ eyi ti PDP ati APC duro fun. Awọn eeyan kan naa, agbada kan naa, fila pupa kan naa, nitori naa, kii ṣe emi nikan, gbogbo Naijiria lo ti ri imọlẹ naa.”