Anthony Joshua lu Otto Wallin lálù dákú, àmọ́ Deontay Wilder fìdírẹmi láìròtẹ́lẹ̀

Oríṣun àwòrán, getty images
Afẹṣẹ ku bi ojo n ni, Anthony Joshua rọ ojo ẹṣẹ le alatako rẹ, Otto Wallin lori debi pe o lu u ni alu daku ni ipele karun un ija wọn.
Amọ, ọrọ ko ri bẹ pẹlu gbajugbaja Deontay Wilder lẹyin Joseph Parker fi ẹṣẹ dara si i lara lairotẹlẹ.
Joshua lu Wallin debi wí pe nigba ti ẹṣẹ wọ lara tan ni ipele karun un ija naa ni olukọni rẹ at'awọn to ba a wa gbe kuro loju ija ti wọn si gba pe Joshua lo bori.
Ilumọọka onija UFC, Conor McGregor ati gbajugbaja agbabọọlu n ni, Cristiano Ronaldo lo jokoo sẹgbẹ ara wọn lati wo ija naa nibi ti AJ ti n fi ẹsẹ ku bi ojo sori Wallin ni Saudi Arabia.
Lọgan ti ija naa bẹrẹ ni Joshua ko beṣubẹgba ti o si bẹrẹ sí ni lu Wallin bi apo ẹwa lati ipele kíni.
Niṣe ni ẹsẹ Wallin bẹrẹ si ni gbọn pẹpẹ latari ẹṣẹ ti o n wọ ọ lara.
Bayii ni AJ n gbadun ara rẹ ti o n sii lo ọwọ ọtun ati osi lati fi lu Wallin ni aludẹ.
Bi Joshua ṣe fakọyọ ninu ija rẹ jẹ iyalẹnu fun ọpọlọpọ lẹyin to ti n tiraka ninu awọn ija to ti ja sẹyin laipẹ.
Deontay Wilder fidirẹmi lairotẹlẹ
Iyalẹnu lo jẹ fun ọpọlọpọ awọn ololufẹ Wilder ati ẹṣẹ kikan pẹlu ọna ti Wilder fi jẹ ajẹtun iya lọwọ Joseph Parker.
Koda, Joshua gan an fẹnu si ọrọ naa pe Wilder le fidirẹmi ni tootọ, amọ yoo tun pada dide.
Joshua ni oun le ṣe Wilder bi ọṣẹ ṣe n ṣoju bayii, amọ, ibi gíga ni oun n wo lọwọ yii.
Gbogbo oludajọ ija naa ni wọn fi idi rẹ mulẹ pe Parker ni o borí ninu ija ọhun.
Koda, awọn to ṣagbatẹru awọn idije ẹṣẹ kikan yii ti ṣeto silẹ fun ija laarin Wilder ati Joshua ni ireti wi pe awọn mejeeji ni yoo borí ninu ija wọn.
Ṣugbọn ọrọ bẹyin yọ lẹyin ti Wilder ni ijakulẹ ninu ija rẹ ti Joshua si borí.
Ẹwẹ, onigbọwọ ija fun Joshua, Eddie Hearn kede lẹyin ija awọn mejeeji pe abẹṣẹku bi ojo ọmọ Croatia, Filip Hrgovic ni Joshua yóò kojú bayii fun bẹniiti IBF to wa nilẹ.
Wilder wọ inu gbọngan ija pẹlu ade lori rẹ ṣugbọn o ti to ọdun mẹrin bayii ti o ti ṣe bi ọba lagbo ẹṣẹ kikan.
Iṣẹju mẹta pere ni Wilder fi kan ẹṣẹ lati bi ọdun meji sẹyin.
Ohun to daju ni pe ija laarin Joshua ati Wilder ti ọpọ eeyan fẹ wo ma le waye ni kopẹ kopẹ.

























