Victor Osimhen, atamátàsé ikọ̀ Super Eagles gba àmì ẹ̀yẹ agbábọ́ọ̀lù tó ta lẹ́nu jùlọ ní Italy

Oríṣun àwòrán, Getty Images
- Author, Isaiah Akinremi ati Emmanuel Akindubuwa
- Role, BBC Sport Africa
- Reporting from, Lagos
Atamatase agbabọọlu ọmọ ilẹ Naijiria nni, Victor Osimhen, ni wọn ti de lade agbabọọlu to mọọ gba julọ (AIC) lorilẹede Italy fun ipa to ko fun ikọ agbabọọlu Napoli ni saa to kọja latọwọ ẹgbẹ awọn agbabọọlu nilẹ naa.
Ogunnagbongbo ninu ikọ Super Eagles naa lo gba ami ẹyẹ ọhun lalẹ ọjọ Aje lẹyin to ran ẹgbẹ agbabọọlu rẹ lọwọ lati gba ife ẹyẹ orilẹede naa fun igba akọkọ lẹyin ọdun mẹtalelọgbọn.
Osimhen lo ri awọn he nigba mẹrindinlọgbọn ni idije Serie A ọdun 2022-3, leyi to ju akọọlẹ ti George Weah ni gẹgẹ bii adulawọ to ri awọn he julọ nilẹ naa.
Atamatase tẹlẹri fun ẹgbẹ Lille ati Wolfsburg ọun ni adulawọ akọkọ ti yoo gba ami ẹyẹ yii leyi to muu dara pọ mọ awọn eeyan bii Zlatan Ibrahimovic, Andrea Pirlo, Christiano Ronaldo ati Rafael Leao to gba a lọdun to kọja.
Osimhen kọja soju opo X rẹ lati wi pe “Mo dupẹ lọwọ yin fun idanimọ ati idalọla yii, mo dupẹ lọwọ ẹbi, ọrẹ ati ẹyin ololufẹ mi fun ibo ati atilẹyin”.

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Pẹlu ami ẹyẹ AIC yii lẹyin to ṣe ipo kẹwa nibi ami ẹyẹ Ballon’d’Or, Osimhen ni yoo ni afojusun didi ọmọ Naijiria akọkọ ti yoo gba ami ẹyẹ CAF fun ọkunrin to gba bọọlu julọ nilẹ adulawo lẹyin Nwankwo Kanu lati ọdun 1999.
Ẹwẹ idunnu ṣubu layọ fun ile Africa ni bi Tabitha Chawinga ọmọ orilẹede Malawi ṣe gba AIC obinrin to mọọ gba ju lọ lẹyin to pari saa to kọja bii agbabọọlu to gba bọọlu wọnu awọn ju lọ pẹlu ami ayo mẹtalelogunfun ẹgbẹ agbabọọlu obinrin ti Inter Milan.
Atamatase ọmọ ọdun mẹtalelogun naa ti Paris Saint-Germain n yalo lọwọ yii ni obinrin ilẹ Africa akọkọ ti yoo rawọn he ju lọ lorilẹede Italy.
Ẹwẹ, ohun iyalẹnu lo jẹ pe ajọ CAF ni ko ri ti Chawinga ro bi ko ṣe si orukọ rẹ ninu awọn obinrin ti yoo duje fun agbabọọlu obinrin ọmọ Africa to mọ bọọlu gba ju.
Awọn to ba yege nibi ami ẹyẹ CAF ni wọn yoo fi oju wọn han nibi ayẹyẹ ti yoo waye lọjọ kọkanla oṣu kejila nilu Marrakesh, lorilẹede Morocco.














