Èèyàn mẹ́fà lugbadi àrùn Diphtheria nipinlẹ Eko.

Diphtheria

Oríṣun àwòrán, Others

Dokita Abiola Idowu tọ jẹ Ọga agba fun ile iṣẹ ti ohun risi abẹwo si awọn ibudo ilera ati iforukosile fun awọn ile iwosan ipinlẹ Eko ti kede pe Ipinlẹ Eko ti ni akọsilẹ aarun ti wọn n pe ni aarun Diphtheria.

Ẹka naa ti wọn n pe ni Health Facility monitoring and acreditation Agency,HEFAMAA lo kede aarun tuntun naa nipinlẹ Eko

Aisan Diphtheria ni Dokita Abiola sọ wi pe o ti mú eeyan mẹfa nipinle Eko ti awọn mẹta ti dagbere faye.

Ninu atẹjade ti Dokita Abiola fi lede, o ni awọn ọmọde lati ọdun meje si mẹrinla ni aisan na mu laarin oṣu kẹwaa ọdun 2022 sì akoko yii.

Abiola rọ awọn ti o n ṣiṣẹ iṣegun lati ṣe akiyesi irufẹ aisan Diphtheria naa ki won si wa ni iṣọra.

Diphtheria jẹ arun ti o wa nipasẹ exotoxin ti kokoro arun Corynubacterium diphtheriae faa.

Ọpọ igba ni aarun Diphtheria ma n waye latari afesi atẹgun tabi lati ọdọ ẹnikan si ẹnikeji o tun ma n takiri nigbati omi ara ba kan ara ẹlomiran.

Abiola rọ awọn dokita lati tete fi to awọn oṣiṣẹ ajo ti o gbogun ti aarun Diphtheria to wa ni ijọba ibilẹ leti ti wọn ba kofiri rẹ.

O ni ajọ to n gbogun ti aarun ni orilẹ-ede yii NCDC, ti fi oogun ti yọ gbogunti aarun Diphtheria ọgọrun ransẹ si ipinlẹ Eko, ti wọn si ti wa ni yara ipamọ Bio-bank ipinle Eko