Kojú ọ̀wọ́ngógó pẹ̀lú àwọn oúnjẹ aṣaralóòre yìí tí owó wọn kò wọ́n rárá

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 4

Láti ìgbà tí Ààrẹ Donald Trump ti gba àkóso ìjọba Amẹ́ríkà ní ìbẹ̀rẹ̀ oṣù Kìíní, ọdún 2025 yìí ló kéde àwọn ìgbésẹ̀ kan tí yóò ní ipa gidi lórí àwọn orílẹ̀ èdè Africa.

Lára irúfẹ́ ìkéde yìí ni pé Amẹ́ríkà kò ní pèsè ìrànwọ́ fún àjọ UNICEF mọ́ láti máa pèsè oúnjẹ fún àwọn ọmọdé tí kò rí oúnjẹ jẹ ní àwọn orílẹ̀ èdè tí ọrọ̀ ajé wọn kò dàgbà.

Lópin ọ̀sẹ̀ tó kọjá ni UNICEF wá kéde pé ó ṣeéṣe káwọn ohun èlò ìrànwọ́ tó wà ní ìkáwọ́ òhun tán láàárín oṣù méjì sí àsìkò yìí.

Èyí tó túmọ̀ sí pé àwọn ọmọdé tó lé ní mílíọ̀nù kan ni ìgbésẹ̀ Amẹ́ríkà yìí yóò ṣàkóbá fún ní Nàìjíríà.

Yàtọ̀ sí ìgbésẹ̀ Amẹ́ríkà yìí, ọ̀wọ́n gógó pàápàá lórí oúnjẹ tó ń bá Nàìjíríà fínra wà lára àwọn nǹkan tó ń fa ebi ọpàgbà fọwọ́ mẹ́kẹ́ tó ń bá ọ̀pọ̀ ìdílé fínra.

Èyí ló mú wa ṣe àgbéyẹ̀wò àwọn oúnjẹ tó ń ṣe ara lóore, tí owó wọn kò sì gunpá jù ní àsìkò yìí táwọn èèyàn le máa jẹ.

Àwọn oúnjẹ wo ni kò wọ́n níye?

Bí ọ̀wọ́n gógó oúnjẹ ṣe ń lékún ní gbogbo ìgbà tí owó tó ń wọlé fún èèyàn kò sì lékún jẹ́ kí ó ṣòro láti máa rí àwọn oúnjẹ tó dára jẹ.

Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé gbogbo oúnjẹ ló ti gbówó lórí, Dókítà Hadejia ní àwọn oúnjẹ kàn wá tí owó wọn kò ì tíì kọjá àfaradà, tí wọ́n sì ṣaara lóore.

Ó ní àwọn oúnjẹ tó dára, tó sì tún máa ń pèsè okun fára tí owó wọn kò sì wọ́n púpọ̀ ni watermelon, ìgbá, ànọ̀mọ́ àti cabbage.

Àwọn mìíràn ni jéró, àgbàdo, ẹ̀wà sóyà, ẹ̀fọ́ úgú, ẹ̀fọ́ tẹ̀tẹ̀, ilá, àti ẹ̀gẹ́. Ó ní síse àpapọ̀ àwọn oúnjẹ yìí àti mímu omi dáadáa ṣe pàtàkì fún ìlera tó péye fún àwọn ìyá tó ń tọ́mọ lọ́wọ́.

Àwọn oúnjẹ tí ẹ lè fi owọ pọ́ọ́kú pèsè rèé:

  • Ìrẹsì alásèpọ̀

Ìrẹsì jẹ́ oúnjẹ tí ọ̀pọ̀ èèyàn fẹ́ràn láti máa jẹ ní Nàìjíríà.

Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé owó ìrẹsì kò dínwó púpọ̀, ó jẹ́ oúnjẹ tó gbajúmọ̀ tí ọ̀pọ̀ máa ń jẹ lójúmọ́.

Síse ìrẹsì alásèpọ̀, èyí tí èèyàn fi ata, ìsebẹ̀, òróró, àtàwọn èròjà míì tó fi mọ́ nǹkan ìjẹun bíi ẹyin, ẹja tàbí ẹran gbé sọ́hùn-ún lyóò fún èèyàn ní àwọn èròjà aṣara lóore bíi Carbohydrate, protein, àti vitamin.

  • Ẹ̀wà

Ẹ̀wà jẹ́ ọ̀kan lára àwọn oúnjẹ tí owó rẹ̀ kò gun ipá jù lásìkò yìí.

Ẹ̀wà jẹ́ oúnjẹ tó máa ń pèsè èròjà aṣara lóore protein.

Bákan náà ló jẹ́ oúnjẹ tí èèyàn le jẹ́ pẹ̀lú àwọn oúnjẹ mìíràn láti jẹ́ kí èèyàn tètè yó àti láti ṣe àfikún èròjà aṣara lóore tí èèyàn fẹ́ rí lára oúnjẹ mìíràn.

Èèyàn le jẹ ẹ̀wà pẹ̀lú iṣu, ìrẹsì, dòdò, gààrí, òdùnkún, àgbàdo àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ, kódà èèyàn tún le fi se ọbẹ̀ gbẹ̀gìrì láti fi jẹ òkèlè.

  • Àsáró

Àsáró náà jẹ́ oúnjẹ tí èèyàn le sè pẹ̀lú owó tí kò pọ̀, tí èèyàn yóò sì jẹ àǹfàní àwọn èròjà aṣara lóore láti ara rẹ̀.

Èèyàn le lo iṣu láti fi se àsáró tàbí lo ànọ̀mọ́ láti fi se é.

  • Ẹba àti ẹ̀gúsí

Lára ọbẹ̀ tó gbajúmọ̀ káàkiri Nàìjíríà ni ẹ̀gúsí wà.

Èèyàn lè se ọbẹ ẹ̀gúsí pẹ̀lú ẹ̀fọ́ tàbí kí èèyàn se é lásán.

Bákan náà ni èèyàn le fi ẹja tabi ẹran se ọbẹ ẹ̀gúsí.

Kò sí òkèlè tí kò lọ pẹ̀lú ọbẹ̀ ẹ̀gúsí àmọ́ ẹba jẹ́ oúnjẹ olówó pọ́ọ́kú, tí yóò sì pèsè àwọn èròjà aṣara lóore táwọn òkèlè mìíràn náà yóò pèsè.

  • Ẹ̀kọ àti mọ́ínmọ́in

Gẹ́gẹ́ bí a ṣe sọ ṣáájú pé ẹ̀wà jẹ́ oúnjẹ tó ṣe é lò láti fi pèsè oríṣiríṣi oúnjẹ.

Oúnjẹ mìíràn tí èèyàn le sè látara ẹ̀wà tún ni mọ́ínmọ́ín.

Ẹ̀kọ àti mọ́ínmọ́ín náà jẹ́ oúnjẹ tó dára fún àgọ́ ara, tó sì máa ń ṣe ara lóore.

Yàtọ̀ sí mọ́ínmọ́ín, àkàrà náà jẹ́ oúnjẹ olówó pọ́ọ́kú tí èèyàn le jẹ pẹ̀lú ẹ̀kọ tàbí búrẹ́dì tàbí gààrí.

  • Ilá alásèpọ̀

Lára ọbẹ̀ tí ó ṣe ara lóore púpọ̀ ni ọbẹ̀ ilá alásèpọ̀ náà wà, ó jẹ́ ọbẹ̀ tí owó tí èèyàn le fi sè é kò gúnpá, tí èèyàn sì lè fi jẹ ọ̀pọ̀ òkèlè.

  • Ẹ̀fọ́ rírò

Kìí ṣe ohun tuntun mọ́ pé ẹ̀fọ́ rírò jẹ́ ọ̀kan lára àwọn ọbẹ̀ tó dára fún ìlera pípé àti àlááfíà ara.

Ọ̀pọ̀ èròjà aṣara lóore ni ó kún inú ẹ̀fọ́ tó sì jẹ́ pé èèyàn le fi owó kékeré pèsè, tó sì ṣe é jẹ ọ̀pọ̀ oúnjẹ.

Ní ìkádìí, ó sàn láti dáná nílé ju kí èèyàn máa ra ara jẹ lọ, èyí yóò mú àdínkù bá iye tí èèyàn máa ná lọrí oúnjẹ, tí èèyàn yóò sì jẹ oúnjẹ aṣara lọore pẹ̀lú owó tí kò guni lára.