You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Ojú dúdú, ẹsẹ̀ funfun - Ẹ wo nnkan tó mú ìyá ọlọ́mọ́ mẹ́fà bóra fún gbogbo ọmọ rẹ̀
Abamọ ti gbẹyin ọrọ fun iyaale ile kan, Fatima, ti a fi orukọ idile bo laṣiiri.
Àwọ̀ awọn ọmọ mẹfa ti obinrin naa bi ti di kalan-kini bayii, nitori ipara borabora to fi n pa wọn lara lasiko kan.
Gẹgẹ bi Fatima to n gbe nipinlẹ Kano ṣe ṣalaye, o ni titi kan ọmọ oun ti ko ju ọmọ ọdun meji lọ ni awọ rẹ ti bajẹ bayii.
Àpá oriṣiiriṣii ni ipara naa ti da si ọmọde naa lara bi iya rẹ ṣe sọ.
Iya ọlọmọ mẹfa ti ọjọ ori rẹ jẹ mejilelọgbọn (32), ṣalaye pe nibi ti nnkan ti bajẹ de lara awọn ọmọ naa, aṣọ ni ọkan ninu awọn ọmọbinrin oun maa n da boju to ba fẹẹ jade, kawọn eeyan maa baa ri oju rẹ to ti jona.
Awọ ọmọbinrin rẹ keji yipada lẹyin ara bibo naa, o dudu ju bo ṣe wa tẹlẹ lọ, amọ ti ibi oju rẹ da funfun lọtọ, nigba ti ete ati ẹsẹ funfun.
Ọmọ ọdun meji to n tọ lọwọ paapaa ti ni egbo ni gbogbo ara. Inira lo n jẹ fun ọmọ naa nitori awọn egbo naa ko ti i san.
Ki lo waa de ti Fatimo ko ara rẹ sinu idaamu yii? Eyi ni alaye to ṣe fun BBC.
'Ẹgbọ́n mi bí àwọn ọmọ pupa, ọmọ dúdú lèmi sì ń bí'
"Nigba ti ẹgbọn mi obinrin n bi awọn ọmọ tiẹ, gbogbo wọn ni wọn pupa, ṣugbọn awọn ọmọ dudu lemi ṣaa n bi.
"Mo ṣakiyesi pe iya mi fẹran awọn ọmọ ẹgbọn mi yẹn ju awọn ọmọ temi lọ nitori awọn ọmọ yẹn pupa.
"Eyi maa n dun mi pupọ.
"Ohun to fa a ti mo fi bẹrẹ si i lo ipara to le mu awọn ọmọ temi naa pupa fun wọn niyẹn"
Fatimọ ṣalaye pe oun maa n ra awọn ipara naa nile itaja kan ni Kano, lai jẹ pe dokita kankan sọ iru eyi toun le lo fun wọn.
O ni funra oun loun n ra ipara borabora to wu oun fun wọn.
Nigba to bẹrẹ si i lo o, o ni o ṣiṣẹ, iya wọn agba to fẹran awọn ọmọ pupa si bẹrẹ si i fẹran awọn ọmọ tiẹ naa.
Ṣugbọn nigba to ya, àpá bẹrẹ si i han lara awọn ọmọ naa, awọ ara wọn si n jọ eyi to ti jona.
Nibi tọrọ naa de duro bayii, Fatimo loun n kabaamọ igbesẹ ara bibo toun gbe naa, nitori aburu to ṣe lara awọn ọmọ oun.
" Awọn ọmọ mi obinrin meji ti padanu ọkọ to yẹ ki wọn fẹ, awọn ọkunrin n sa fun wọn ni, wọn o fẹẹ ba awọn ti wọn ro pe wọn n lo oogun oloro ṣe.
Yatọ si pe o kabaamọ iwa rẹ, Fatima sọ pe titi lae ni iwa toun hu fawọn ọmọ naa yoo maa ba ọkan oun jẹ, paapaa bi awọn apa ti ipara da si wọn lara ko ba parẹ mọ.
"Nigba ti mo jẹwọ nnkan ti mo ṣe fun maami, ti mo sọ fun wọn pe iwa wọn lo jẹ ki n bora fun awọn ọmọ mi, ti wọn si gbọ ohun ti ipara naa sọ awọn ọmọ mi da, inu wọn bajẹ, wọn ni ki n ma binu"
"Bo tilẹ jẹ pe mi o lo o fun wọn mọ, ọṣẹ́ ti ipara borabora ṣe lara awọn ọmọ mi ṣi wa nibẹ.
"Mo bẹ awọn obi yooku, ki wọn fi ọrọ mi kọgbọn o"
Fatima lo sọ bẹẹ.
Ìdí mí-ìn táwọn èèyan fi ń bóra
Lorilẹ ede Naijiria, oriṣiiriṣii ipara ati eroja ara bibo lo wa.
Iwadii fi han pe awọn obinrin Naijiria lo n bo ara ju nilẹẹ Africa. Ida mẹtadinlọgọrin (77%) obinrin lo n lo awọn ipara borabora deede lorilẹede yii, bi ajọ ilera agbaye; World Health Organization, ṣe sọ.
Ṣugbọn ki ni idi ẹ ti wọn fi n bora bi eyi, Zainab Bashir Yau, obinrin to ni ileeṣẹ kan ti wọn ti n ri si awọ ara l'Abuja, ṣalaye fun BBC pe:
" Ọpọ eeyan aa maa fi ki eeyan pupa we ki eeyan lowo lọwọ. Eyi maa n jẹ ki wọn sọ awọ wọn di pupa"
"Lati ikoko ni awọn obinrin mi-in ti maa n lo nnkan ibora fawọn ọmọ wọn, ki wọn le tan yoo loju.''
Aajo ẹwà ni awọn mi-in si ro pe awọn n ṣe ti wọn fi n bora.
Awọn orilẹede to pawọ le Naijiria ninu ara bibo ni: Congo-Brazzaville (66%), Senegal (50% )ati Ghana (39%.)
Kí ni àwọn èròjà tó wà nínú ìpara tó ń bóra
Awọn eroja bii corticosteroids abi hydroquinone, to le ṣe ijamba fun ara bi wọn ba pọju maa n wa ninu ipara ibora.
Ni ọpọ ilu, wọn ki I ta awọn eroja naa bi ko ba jẹ pe dokita kọwe fun eeyan lati lọọ ra a wa.
Awọn eroja mi-in ti wọn n lo ninu ipara naa jẹ majele fun awọ ara. Awọn bii: mercury ati kojic acid.
Awọn eroja yii ko ni I ṣe akoba fun awọ ara nikan lasan bi awọn dokita nipa awọ ara ṣe ṣalaye, wọn ni o tun le ba eroja mẹkuri to wa lara jẹ, bẹẹ lo le ba kindinrin eeyan jẹ pẹlu.
Awọ ara le fuyẹ, ko ma ni agbara mọ, eyi ko ni I jẹ ki egbo to ba mu eeyan tete san, o si ṣee ṣe ki Kokoro wọnu egbo naa bi WHO ṣe ṣalaye.
Dokita Leonard Omokpariola, adari ikan ni NAFDAC, sọ pe iṣẹ n lọ nipa bawọn yoo ṣe maa ṣalaye ewu to wa ninu awọn ipara yii fun awọn eeyan.
O ni awọn maa n lọ si ọja lati ko awọn ipara naa kuro nilẹ.
Dokita Leonard ni ṣugbọn wọn maa nira lati da mọ nigba mi-in, nitori wọn ko ni i kọ akọle si i.
Bi eeyan ko ba si gbe iru ipara bẹẹ de yara ayẹwo, ko le mọ ohun ti wọn po pọ ti wọn fi ṣe e.