You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Wò ó bí ohun tí ò ń kọ sórí ayélujára ṣe le dènà gbígba físà rẹ̀ láti kẹ́kọ̀ọ́ l‘Amérika?
Ileeṣẹ ijọba ilẹ Amẹrika, State Department ti kede pe oun yoo pada bẹrẹ si n fun awọn to ba fẹ gba fisa ilẹ naa lọna ati kawe laaye.
Amọ o ni awọn eeyan to nilo fisa ọhun gbọdọ ṣi oju opo ikansiraẹni wọn lori ayelura silẹ fun ayẹwo.
Lara awọn ayẹwo ti ijọba Amẹrika yoo bẹrẹ si n ṣe loju opo ayelujara awọn eeyan ni lati mọ boya wọn n kọ awọn ohun to lodi si "awọn ọmọ Amẹrika, aṣa, ijọba, ileṣẹ atawọn ohun ti Amẹrica gbagbọ ninu rẹ."
Oṣu to kọja ni ijọba Donald Trump gbẹsẹle fifun awọn to ba fẹ kawe ni fisa lọna ati ti ilẹkun mọ awọn to korira orilẹede naa.
Awọn ti ọrọ yii kan julọ ni awọn to fẹ gba fisa labẹ ipin F to jẹ awọn akẹkọọ lati ilẹ okere.
Wayi o, ibere ti ọpọ n beere ni ipa ti igbesẹ yiyẹ oju opo ayelujara wo yoo ni lara awọn to ba fẹ lọ kawe l'Amẹrika, paapaa boya igbesẹ ọhun le mu ki Amẹrika ma fun irufẹ eeyan bẹẹ ni fisa?
Bawo ni ohun ti eeyan n kọ lori ayelujara se le dena gbigba fisa Amẹrika?
Nigba ti BBC Yoruba kan si onimọ nipa irinajo silẹ okeere, to tun jẹ oludari ileeṣẹ Peaceway Travel and Holidays, Oluwatobi Omojeso, o ni igbesẹ naa le pa awọn to ba fẹ gba fisa lara.
O ṣalaye pe ọpọ igba ni awọn akẹkọọ lati ilẹ okere maa n ṣe iwọde tako ijọba Amẹrika, eyii wa lara nnkan to jẹ ki ijọba gbe igbesẹ naa.
O ni "ninu iwadii ijọba Amẹrika, wọn ri pe iwa yii pọ laarin awọn akẹkọọ, ohun ni wọn ṣe wo o pe ki wọn tilẹ to fun awọn akẹkọọ ni fisa, wọn maa kọkọ wadii boya wọn ti wu irufẹ iwa bẹẹ ri.
"Igbesẹ yii lo jẹ ki wọn maa din awọn ti wọn n fun ni fisa ku… ti wọn ba fun eeyan ni fisa gan, wọn ṣi le da irufẹ ẹni bẹẹ pada sile to ba de ẹnubode wọn nitori ọwọ ẹṣọ aṣobode ni agbara wa lati jẹ ki eeyan wọle tabi bẹẹ kọ."
Omojeso sọ pe ti ijọba ilẹ kan ba sọ pe ohun bayii loun ko fẹ, ẹnikẹni ti yoo ba gba fisa ilẹ kan gbọdọ fẹ ohun ti ijọba ilẹ naa n fẹ.
Ohun ti eeyan le kọ sori ayelujara eyi to le ṣakoba fun to ba fẹ gba fisa láti kẹkọọ ni Amẹrika:
Onimọ nipa irinajo silẹ okeere naa wa mẹnuba awọn ohun ti eeyan le kọ soju opo ayelujara rẹ, eyi to le se akoba fun akẹkọọ kan gba fisa ilẹ Amẹrika:
Sisọ ọrọ lori ohunkohun to ba jọ mọ iwa jagidijagan lori ayeluja
Sisọ ọrọ nipa ohun to n waye laarin ijọba Amẹrika ati ijọba ilẹ mii le ṣakoba fun eeyan
O ni ẹnikẹni to ba n ṣe irufẹ nnkan bẹẹ ti ṣẹ si ofin ilẹ Amẹrika lati wọ ilẹ ọhun.
"Imọran mi fun awọn eeyan ni pe ki wọn ṣọ ohun ti wọn maa kọ sori ayelujara nitori ohun ti eeyan n kọ ni wọn fi n ṣedajọ irufẹ ẹni ti eeyan jẹ.
"Pẹlu iriri wa nidi iṣẹ yii fun ọpọ ọdun, a ti ri pe wọn maa n beere orukọ oju opo ayelujara eeyan to ba ti n forukọsilẹ fun fisa.
O si ye wa pe ti wọn ko ba fẹ ṣayẹwo oju opo naa, wọn ko ni maa beere rẹ.
"A ti ri pe o kun ara nnkan ti wọn maa n lo lati mọ boya."
Awọn wo ni ọrọ yii kan gbọngbọn?
Gẹgẹ bii alaye ijọba Amẹrika, awọn ti ọrọ yii kan julọ ni awọn to ba fẹ lọ kawe l'Amẹrika.
Eyii kan awọn to ba fẹ gba fisa labẹ isọri F.
Wọn ni ọrọ naa yoo tun kan awọn to ba fẹ gba fisa labẹ ipin M, fun ẹkọ iṣẹ ọwọ, atawọn to n le fisa labẹ ipin J.
Ijọba Amẹrika sọ pe igbesẹ ọhun ko ṣẹyin gbigbogun ti awọn ọta ilẹ Amẹrika to n fi iwe boju nilẹ naa.
O le ni miliọnu kan eeyan lati orilẹede to le ni igba to n kẹkọọ lawọn ile ẹkọ Amẹrika laarin ọdun 2023 si 2024.
Ikede yii lo jẹyọ ninu atẹjade ajọ Open Doors to n ṣe akọsilẹ nipa awọn akẹkọọ lati ilẹ okeere.