Ilé ẹjọ́ kéde ọmọ Sanni Abacha gẹ́gẹ́ bíi ojúlówó olùdíje gómìnà nínú ẹgbẹ́ òṣèlú PDP nípìnlẹ̀ Kano

Oríṣun àwòrán, @Imranmuhdz
Ile ẹjọ kan nipinlẹ Kano ti kede pe Mohammed Abacha ni ojulowo oludije sipo gomina ninu ẹgbẹ oṣelu PDP ni ipinlẹ naa.
Ninu idajọ rẹ lalẹ Ọjọbọ, adajọ A.M Liman sọ pe oun ko gba eto idibo abẹnu ti ẹgbẹ naa ṣe ṣaaju to kede Sadik Wali gẹgẹ bii oludije ẹgbẹ naa wọle.
Adajọ naa tun paṣẹ fun ajọ to n ri si eto idibo, INEC, pe ko kede Abacha gẹgẹ bi ojulowo ẹni ti yoo du ipo naa ninu ẹgbẹ ọhun.
Idajọ naa to yẹ ko waye laago mejila ọsan ni wọn sun si aago mẹrin irọlẹ.
Gbogbo ibeere ti ẹni to gbe ẹjọ naa wa sile ẹjọ bere fun ni adajọ fi fun un.
Mohammed Abacha ni olupẹjọ, nigba ti Wali, ajọ INEC ati ẹgbẹ oṣelu PDP jẹ olujẹjọ.
Ninu ipẹjọ naa ni Abacha ti ke si ile ẹjọ ọhun pe ko kede oun gẹgẹ bii ẹni to jawe olubori ninu eto idibo abẹle ti wọn ṣe ṣaaju, ko si paṣẹ fun INEC pe ko fontẹ lu oun bi oludije.
O ni gẹgẹ bo ṣe wa ninu iwe ofin eto idibo ọdun 2022, oun lo ni iye ibo to pọju ninu eto idibo abẹle ti wọn ṣe lọjọ karundinlọgbọn, oṣu Karun un, ọdun 2022 yii.
Mohammed Abacha jẹ ọkan lara awọn ọmọkunbrin Sanni Abacha, to jẹ olori orilẹ-ede Naijiria lasiko ijọba ologun to ko to dagbere faye lọdun 2008.












