Ẹ jọ̀wọ́, ẹ tú àwọn olùwọ́de #Endsars sílẹ̀, ọ̀dọ̀ yín ni wọ́n ti kọ́ nípa ṣíṣe ìwọ́de - Shehu Sani rọ Tinubu

Oríṣun àwòrán, Shehu Sani/Facebook/GettyImages
Sẹnetọ nigba kan lorilẹede Naijiria, Shehu Sani ti rọ Aarẹ Bola Tinubu lati forgin awọn oluwọde #Endsars to si wa ni ahamọ agbofinro.
Ni oṣu kẹwaa ọdun 2020, ọpọ awọn ọdọ gunle ifẹhonuhan kaakiri orilẹede Naijiria lati tako ẹka ileeṣẹ ọlọpaa Sars.
Lasiko iwọde naa, awọn ijọba ipinlẹ kan kede konilegbele lati dena de kikọlu ofin, ati ki alaafia si le jọba lasiko naa,
Ọpọ awọn ọdọ ni ọwọ awọn agbofinro tẹ ni awọn ilu bi Eko, Rivers ati Ibadan.
Pupọ ninu awọn oluwọde naa lo si wa ni ahamọ, ti wọn jẹjọ lori orisirisi ẹsun to rọ mọ iwọde naa.
Nigba to n sọrọ ni ayẹyẹ ayajọ ijọba awarawa, Sani ni pupọ awọn ọdọ yii lo kọ bi wọn se n ṣe iwọde bii ti eyi ti wọn se tako Sars lati ọwọ awọn ohun ti wọn mọ nipa Aarẹ Bola Tinubu, ẹni ti Shehu Sani ṣapejuwe gẹgẹ bii Baba fun iwọde, to si wa lara awọn to lewaju ninu siṣe iwọde lati gba ijọba kuro lọwọ ologun.
“Aarẹ, awọn ọdọ kan si wa ni ahamọ nitori iwọde EndSars. Ọmọde ni wọn ni wọn n ṣe ifẹhonuhan fun idajọ ododo, ominira ati ijọba awarawa.
“Awọn ọdọ to n ba se iwọde lonii Naijiria ni lati wa kọ ẹkọ lati ọwọ Aarẹ nitori Aarẹ ni Baba fun iwọde lorilẹede Naijiria.
“Ẹ ṣe nnkan si ọrọ yii. Ẹ fun ni ominira, ẹ forijin wọn.
“Ẹ yin ni ẹ kọ wa pe ka dide fun ẹtọ wa, ka si ija fun ohun ta gbagbọ ninu . Fun idi eyi, awọn ọmọ yin ati awọn ọmọ-ọmọ ni awọn ọmọ yin, ẹ forijin wọn.”
Orin orilẹede ko to lati mu isọkan ba Naijiria
Shehu Sani tun tẹsiwaju ninu ọrọ rẹ pe yiyi orin orilẹede pada si omiran ko to lati mu isọkan ba orilẹede Naijria.
Sani rọ Aarẹ nipa pataki ri ri pe isọkan, idọgba ati idajọ ododo wa lorilẹede Naijria.
“Aarẹ, mo fẹ pe akiyesi yin. Orin orilẹede ko le so wa pọ. Adura tabi iwe ofin ilẹ wa ko so wa pọ.
“Ominira wa lo se so wa pọ, a ni gbe orilẹede yii lori idajọ ododo ati idọgba. Ọpọ awọn ọdọ oni ko mọ ohun ti a la kọja lati ri pe ijọba awarawa wa lorlẹede Naijria.
“O ṣe koko ka pe akiyesi awọn eeyan ti ko si nibẹ nigba ti a n la awọn nnkan wọnyi kọja.”















