Gómìnà Abiodun bẹ̀rẹ̀ àtúnkọ́ ilé MKO Abiola l‘Abeokuta

Oríṣun àwòrán, @DapoAbiodunCON
Gomina Dapo Abiodun ti ipinlẹ Ogun ti paṣẹ fun ile iṣẹ to n ri sọrọ ile gbigbe ni ipinlẹ naa lati lọ ṣe atunkọ ile oloogbe MKO Abiola to wa ni agbegbe Gbagura, Oja Agbo ilu Abeokuta laifi akoko ṣofo rara.
Nipa bi wọn ti n gbaradi fun ti pọpọsinsin ayẹyẹ ayajọ eto ijọba tiwa n tiwa.
Tẹẹ ba gbagbe, ki Aarẹ Muhamadu Buhari to kuro lori aga iṣakoso ilẹ Naijiria lo ti kede ọjọ kejila Oṣu kẹfa gẹgẹbi ọjọ ti ayẹyẹ isaamin eto ijọba awarawa yoo maa waye.
Leyi to tako ti ọjọ kọkandinlọgbọn Osu karun to wa tẹlẹ lati maa fi ṣeranti ipa ribiribi ti Abiola ko nipa bi eto ijọba awarawa yoo ti wa ni ilẹ Naijiria.

Oríṣun àwòrán, facebook/dapoabiodunmfr
Kí ni ẹbí MKO Abiola sọ?
Ilu Abeokuta tii ṣe olu ilu ipinlẹ Ogun ni akọwe iroyin agba fun Gomina, Lekan Adediran ti fọwọsi atẹjade ti gbolohun naa wa lọjọ iṣẹgun.
Gẹgẹbi atẹjade ọhun ti wi, Gomina Abiodun n fẹ ki wọn ṣe atunkọ ile mọlẹbi Aarẹ ọna kakanfo ti ilẹ yoruba to doloogbe naa, ko lee dun wo loju, ki awọn to ti ja fita fita fun ijọba tiwa n tiwa lee maa wa sibẹ fun ayẹyẹ.
Ẹwẹ, Alhaji Tajudeen Abiodun tii ṣe igbakeji olori ẹbi naa, safihan idunu rẹ si inurere ijọba ipinlẹ Ogun.
O tọka sii wi pe kii ṣe ayipada nikan kọ ni atunkọ ile naa yoo mu ba wọn, o ni yoo tun bu iyi kun agbegbe ọhun nipa bi wọn ti ṣiṣe atunṣe lori ojuṣan agbara ibẹ eyi to ti ṣaaju da wo.
“A dupẹ oore lọwọ ijọba ipinlẹ Ogun, wọn tun orule ṣe, wọn tun bawa gbe awọn ferese atijọ kuro, gbogbo ile lo ti gbawọ tuntun wọ.
Ọkan lara ọmọ bibi oloogbe naa, Ameen Abiola sọ pe ẹbi wọn fẹmin imoore han si ijọba fun ananwọsi naa, leyi ti wọn ṣe lati mu ifẹsẹrinlẹ ba awọn apẹrẹ rere ti baba rẹ to doloogbe fi silẹ.
Gẹgẹbi ọrọ rẹ, O ni gbogbo igba ni ẹbi wọn yoo maa dupẹ lori eyikeyi akitiyan ti wọn ba sa lati mu iranti baba wọn wa sọkan awọn eeyan.
Ta ni MKO Abiola?

Oloye Moshood Kashimawo Olawale Abiola je gbajugbaja oniṣowo, oloselu, o tun jẹ ẹlẹyinju aanu ẹda.
Ojo kẹrinlelogun osu kejọ Ọdun 1937 ni a bii nilu Abeokuta ipinle Ogun.
Igbagbọ awọn eeyan ni wi pe oun lo jawe olubori nibi eto idibo aarẹ lọdun 1993 eyi ti adari ologun igba naa Ibrahim Babangida fagile.
Lẹyin eyi lo kede ara rẹ bi ẹni to gbegba oroke ṣugbọn ti won fi pamọ sinu atimọle, nibẹ ni ẹmi rẹ bọsi lọjọ keje osu keje ọdun 1998, ti eredi iku rẹ si lọwọ bakan bakan ninu.















