Aunty Ramota bọ́ síta sọ̀rọ̀ lẹ́yìn awuyewuye pé ó fọn ìdí

Aworan Ramota Adetu

Oríṣun àwòrán, Instagram

Idunu subu laayọ fun ọpọ awọn ololufẹ gbajugbaju oṣere tiata, Ramota Adetu, ẹni ti ọpọ mọ si Aunty Ramota nigba to bọ sita sọrọ lẹyin ti iroyin to sọ pe o fọn idi lu sita lori ayelujara.

Iroyin naa ni pe o wa ni ẹsẹ kan aye ẹsẹ kan oorun lẹyin to ṣe iṣẹ abẹ lati fọn idi nile iwosan kan niluu Ikorodu nipinlẹ Eko.

Fọnran to lu sita ṣafihan bi wọn ṣe n gbe Ramota wọ wọọdu, ti wọn si n fa omi si lara ni ile iwosan.

Ọjọ kẹwaa oṣu kẹfa ni iroyin naa jade sugbọn Ramota ti bọ sita lati sọrọ lori iṣẹlẹ naa.

O ṣalaye pe ọrọ ko ri bẹẹ rara ati pe oun ko fọn idi.

"Ko si nnkan to se mi, ara mi ree o, n ko fọn idi"

Ramota ninu fọnran fidio tuntun to gbe sori Ayelujara, dupẹ lọwọ awọn ololufẹ rẹ fun bi wọn se gbaruku ti i, to si jẹ ko di mimọ pe alaafia ni oun wa.

O fi ara rẹ han, to si jẹ ko di mimọ pe ko si ohunkohun to ṣe tabi ṣe ilera rẹ.

“Ẹni ololufẹ mi, ẹ ṣe o, ko si nnkan to ṣe mi

“Ara mi ree, ko si nnkan to ṣe mi.”

Saaju ni gbajugbaja adẹrinposonu, Ganiyu Kehinde Morufu, ẹni ti ọpọ mọ si ijoba Lande ni o ko mọ ohunkohun nipa ohun to ṣẹlẹ si Ramota.

Ijoba Lande ni awọn eeyan to wa pẹlu gbajugbaja oṣere tiata Aunty Ramota ni oun da lẹbi lori iroyin to lu sita pe Aunty Ramota lọ fọn idi.

Pupọ awọn ololufẹ Ramota ni wọn ti sọrọ lori iṣẹlẹ sugbọn ti wọn inu wọn dun lati ri Ramota pada loju opo ayelujara.

Skip Instagram post
Allow Instagram content?

This article contains content provided by Instagram. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read Instagram cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: The BBC is not responsible for the content of external sites.

End of Instagram post