Kí ni ìdí tí ìjọba àpapọ̀ fi gbé ilé ìtajà Sahad Stores tì pa nílùú Abuja?

Aworan

Oríṣun àwòrán, UKAN KURUGH

Ajọ to n daa bo ẹtọ awon onibaara ni, Federal Competition and Consumer Protection Commission (FCCPC) ti sọ kọkọrọ si ile itaja kan niluu Abuja, to jẹ olu ilu Naijiria.

Ẹsun ti wọn fi kan ile itaja Sahad Stores ni pe wọn n fowo kun iye owo to yẹ ki wọn ta awọn ọja wọn fun awọn araalu.

Awọn osisẹ FCCPC tu sita ni agbegbe Garki 2, ti wọn si ti ile itaja naa lọjọ kẹrindinlogun ọdun 2024.

Ọga ileeṣẹ naa, Adamu Abdullahi salaye pe bi awọn ile itaja se n fi owo kun owo ọja, n ṣe ipalara fun araalu.

Eyi waye lẹyin ti Aarẹ Tinubu gbe aṣẹ kalẹ pe ki awọn ọga agba ileeṣẹ ẹsọ alaabo fọwọsowọpọ pẹlu awọn gomina ipinlẹ lati ri daju pe ounjẹ wa ni ilu.

Airi ounjẹ jẹ lo ti n ba orilẹede Naijiria finra, ti ọpọ awọn si ti bẹrẹ lati ma se ifẹhonuhan lori ọwọn gogo ounjẹ kaakiri orilẹede Naijiria.

Ọjoojumọ ni owo gun owo ounjẹ- Araalu

Owo to n gun iye owo ounjẹ lasiko yii lo jẹ eyi ti ko ti waye aarin ọgbọn ọdun. Eyi lo gbode lẹyin ti Aarẹ Tinubu yọ owo iranwọ epo bẹntiroolu ati awọn igbesẹ ijọba mii.

Fun bi oṣu kan bayii, irẹsi to jẹ ounjẹ ti ọpọ eeyan n jẹ ju ti di ẹgbẹrun mẹtadinlọgọrin naira, eyo to pọju iye owo oṣu to kere ju ti ijọba n san fun awọn osisẹ ijọba.

Ikani BBC se abẹwo si awọn ọja ounjẹ lati mọ bi nnkan se n lọ, to ja si pe ọpọ awọn ounjẹ lo ti gbe owo le ori, ti awọn olutaja ati oniraja si mu igbe bọ ẹnu.

Awọn olutaja to ba wa sọrọ salaye pe ojoojumọ ti owo n gun nnkan ti awọn n ta , ti ọpọ awọn araalu ni ko si wa sinu ọja bi ti tẹlẹ mọ.

“Ẹ wo bi ọja wa se gbẹ, eeyan melo ni ẹ ri to wa ra ounjẹ? Eyi ko sẹyin bi nnkan se wọn, ti ko si si owo lati ra ounjẹ. Awọn eeyan to n ra apo irẹsi tẹlẹ ko ni igbara rẹ mọ.

Fun awọn oluraja ti a ba pada ninu Ọja salaye ipo ti awọn wa bayi ni lati ra ohun ti agbara wọn ba ka.

“Lasiko yii, ohun ti agbara rẹ ba ka ni nitori ko si owo.”

Ọpọ ifẹhonuhan lo ti waye nitori ọwọngogo ounjẹ ni agbegbe kan lorilẹede Naijiria.