Ilé ìgbìmọ̀ aṣòfin South Africa kéde Cyril Ramaphosa gẹ́gẹ́ bíi Ààrẹ

Aworan Aarẹ orilẹede South Africa,k Cyril Ramaphosa

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ile igbimọ aṣofin lorilẹede South Africa ti yan Cyril Ramaphosa gẹgẹ bii Aarẹ orilẹede naa lẹyin ti adehun waye laarin ẹgbẹ oṣelu African National Congress atawọn ẹgbẹ oṣelu alatako yooku.

Ijọba tuntun naa ni Ramaphosa ti ẹgbẹ oṣelu ANC n lewaju fun un, pẹlu ẹgbẹ oṣelu Democartic Alliance ati awọn ẹgbẹ oṣelu yooku.

Ninu ọrọ rẹ, Ramaphosa gbe oriyin fun ajọsepọ naa, to si sọ fun awọn oludibo lati ma reti awọn olori ti yoo sisẹ papọ fun ilọsiwaju orilẹede naa.

Wọn pinnu lori adehun yii nigba ti wahala oṣelu bẹ silẹ, Ti wọn si n jiroro lori pe ta ni yoo lewaju fun ijọba tuntun naa.

Saaju, wọn ti pinnu lori adehun lẹyin ọpọlọpọ ọsẹ ti ọpọ ko mọ ẹgbẹ oṣelu ti ANC yoo jọ fọwọsowọpọ pẹlu lẹyin ti wọn padanu ọpọ ibo ninu eto idibo fun igba akọkọ ni ọgbọn ọdun ni oṣu to kọja.

ANC ni ida ogoji ibo, ti DA si ni wa ni ipo keji pẹlu ibo ida mejilelogun.

Akọwe agba fun ẹgbẹ oṣelu ANC , Fikile Mbalula pe ajọsepọ ni “Igbesẹ nla”.

Eyi tumọ si pe Ramaphosa, ẹni to rọ po Jacob Zuma gẹgẹ bii Aarẹ ati olori ẹgbẹ oṣelu ANC lẹyin ti ija nla waye ni ọdun 2018, lo tun di Aarẹ.

Igbesẹ to ku bayii ni ki Ramaphosa pin ipo ile igbimọ aṣofin, ti awọn ọmọ ẹgbẹ DA yoo si wa laarin wọn.