Ọkùnrin kan gún ìyàwó rẹ̀ pa nítorí omi ní ìpínlẹ̀ Eko

Aworan

Oríṣun àwòrán, others

Ọkunrin kan, Lawrence Itape ni o ti ṣekupa iyawo rẹ lẹyin ti ariyanjiyan waye laarin wọn nitori omi ni agbegbe Ajah ni nipinlẹ Eko.

Itape, ẹni mọkandinlaadọta ni o fi ọbẹ gun iyawo naa titi to fi gbe ẹmi mi lẹyin ti rogbodiyan waye laarin nitori bi lilo omi ṣe safẹrẹ ni agbegbe ọhun.

Agbẹnusọ ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Eko, Benjamin Hundeyin ni kete ti awọn gbọ iroyin ni ikọ ileeṣẹ ọlọpaa gbera lọ si agbegbe naa lati bẹrẹ iwadii.

Hundeyin, ẹni to fi idi isẹlẹ naa mulẹ ni ọwọ ti tẹ ọkunrin naa pẹlu ọbẹ to fi sisẹ ibi naa fun iyawo rẹ.

Bakan lo ni awọn ti gbe oku iyawo lọ si ile oku, Mainland General Hospital, to wa ni Yaba fun ayẹwo ati awọn iwadii miiran.

“Lori iṣẹlẹ naa, a ti gbe afurasi naa lọ si ika ileeṣẹ ọlọpaa ni Panti ni Yaba fun iwadii.

“Oku iyawo naa ti wa ni ile oku Mainland General Hospital fun ayẹwo ati awọn iwadi orisirisi.”