You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Ohun tí a mọ̀ rèé nípa àríyànjiyàn láàrin APC àti Gómìnà Adeleke tó ní sáà àwọn alága ìjọba ìbílẹ̀ APC l'Osun ti parí
Ariyanjiyan si n lọ laarin Gomina Ademola Adeleke ati ẹgbẹ oṣelu APC lori asiko to yẹ kawọn alaga ati kansilọ ijọba ibilẹ to wọle labẹ asia APC lo ni ọfiisi.
Gomina Adeleke sọ pe saa awọn alaga atawọn kansilọ APC naa ti pari wi pe bi wọn tun ṣe wa nipo lodi sofin.
Ẹwẹ, ẹgbẹ oṣelu APC naa da a pada fun gomina wi pe ko si ohun to jẹ bẹẹ rara.
Ohun to ti ṣẹlẹ sẹyin lori ọrọ awọn alaga ijọba ibilẹ ipinlẹ Osun
Ni oṣu Kewaa ọdun 2022 ni awọn eeyan ipinlẹ Osun dibo yan awọn alaga atawọn kansilọ ijọba ibilẹ labẹ asia ẹgbẹ oṣelu APC.
Amọ, gomina Adeleke tu wọn ka lẹyin ti ile ẹjọ giga apapọ wọgile eto idibo to gbe awọn alaga atawọn kansilọ naa wọle.
Lẹyin naa lawọn alaga atawọn kansilọ naa morile ile ẹjọ kotẹmilọrun lati le pada sipo wọn.
Lẹyin o rẹyin, ile ẹjọ kotẹmilọrun dawọn pada sipo wọn loṣu Keji ọdun 2025 to kọja.
Dipo ki wọn pada si ọfiisi wọn lawọn ijọba ibilẹ, awọn alaga atawọn kansilọ PDP tuntun ti wọn jawe olubori ninu eto idibo ti ijọba Gomina Adeleke ṣagbatẹru rẹ ni ijọba ipinlẹ Osun ṣe iburawọle fun.
Bayii ni aawọ bẹ silẹ lẹyin tawọn alaga atawọn kansilọ ẹgbẹ mejeeji faake kọri pe awọn lo yẹ ki awọn wa lawọn ọfiisi ijọba ibilẹ l'Osun.
Lati asiko yii lawọn oṣiṣẹ ijọba ibilẹ labẹ asia ẹgbẹ NULGE ti gunle iyanṣẹlodi ti ijọba apapọ naa si gbẹsẹ le owo oṣooṣu to yẹ ko maa lọ si apo gbogbo ijọba ibilẹ nipinlẹ Osun.
Saa awọn alaga APC ti pari lawọn ijọba ibilẹ - Adeleke
Gomina Adeleke duro lori ẹsẹ rẹ pe lati osu Kẹwaa ọdun 2025 ni saa awọn alaga atawọn kansilọ APC ti pari.
Adeleke sọ pe fifun awọn ijọba ibilẹ ni ominira ko tumọ si gbigbẹsẹ le owo ijọba ibilẹ to wa fun sisan owo oṣu awọn oṣiṣẹ eleto ilera, awọn olukọ atawọn oṣiṣẹfẹyinti.
''Ijọba mi lo ti n sanwo oṣu fawọn oṣiṣẹ ijọba ibilẹ lati ọjọ yii wa.
To ba jẹ wi pe loootọ ni a wa ni ijọba awarawa, ko yẹ kawọn ti araalu ko dibo yan si maa wa lọfiisi lawọn ijọba ibilẹ.
Ẹnikẹni ko lagbara lati fi ọjọ kan ṣoṣo kun saa rẹ lọfiisi labẹ ijọ awarawa to fẹsẹ mulẹ.
Bi bẹẹ kọọ, wọn yoo fọwọ ofin mu iru ẹni bẹẹ, o si le dero ẹwọn.
Awọn agbofinro ko ni daabo bo awọn ti araalu ko dibo yan tabi awọn ti saa wọn ba ti pari nibi ti ijọba awarawa ba ti fẹsẹ mulẹ.
Bi ẹgbẹ oṣelu APC ṣe morile ile ẹjọ lati beere fun afikun saa awọn alaga atawọn kansilọ wọn ti won fawọn ọlọpaa lati ma daabo bo wọn.
Ṣe lo yẹ kawọn agbofinro faye gbawọn alaga atawọn kansilọ ti araalu dibo yan lati bọ si ọfiisi wọn lawọn ijọba ibilẹ,'' Adeleke lo sọ bẹẹ.
APC fesi sọrọ Gomina Adele lori ọrọ saa awọn alaga ijọba ibilẹ
Adari eto iroyin fun ẹgbẹ oṣelu APC, Kola Olabisi, ti fesi lorukọ ẹgbẹ oṣelu naa sọrọ ti Gomina Adeleke sọ.
Ọgbẹni Olabisi sọ pe gomina n ṣi awọn araalu lọna ni pẹlu nnkan to n sọ wi pe saa awọn alaga atawọn kansilọ APC ti pari.
Adari eto iroyin fun ẹgbẹ oṣelu APC ni irọ to jinna si ootọ ni Gomina Adeleke n pa.
''Ni ṣe lo yẹ ki Gomina Adeleke sọ otitọ ati nnkan to wa nibi ọrọ naa wi pe oun ni o lo agbara lati yọ awọn alaga atawọn kansilọ APC ti araalu dibo yan nipo lai fun wọn lanfaani lati wa ojutuu si ọrọ naa nile ẹjọ.
Bakan naa lo yẹ ki gomina tun sọ fawọn eeyan wi pe ile ẹjọ kotẹmilọrun lo dawọn alaga atawọn kansilọ naa pada sipo wọn lọjọ kẹwaa oṣu Keji ọdun 2025.
Lara awọn irọ ti gomina tun pa ni pe awọn alaga atawọn kansilọ APC n wa afikun saa ti wọn yoo lo nipo, tori ẹjọ to wa niwaju ile ẹjọ giga apapọ ilu Osogbo da lori bawọn alaga atawọn kansilọ APC yoo ṣe lo ọdun mẹta to yẹ ki wọn lo.
Nnkan mii to tun yẹ ki gomina sọ fawọn araalu ni pe awọn alaga atawọn kansilọ APC n beere lọwọ ile ẹjọ bo ya o tọna labẹ ofin fun ijọba Gomina Adeleke lati ṣe eto idibo ijọba ibilẹ mii l'Osun nigba ti saa awọn alaga atawọn kansilọ to wa nipo ko tii pari,'' Ọgbẹni Olabisi ṣalaye.
Amọ, Gomina Adeleke si duro lori ẹsẹ rẹ pe saa awọn alaga atawọn kansilọ APC ti pari lati oṣu kẹwaa ọdun 2025.