You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Kí ló ń fàá tí àwọn obìnrin kan fi máà tètè dáwọ ṣíṣe nǹkan oṣù dúró?
Kí ló ń fàá tí àwọn obìnrin kan fi máà tètè dáwọ ṣíṣe nǹkan oṣù dúró?
Akoko yii jẹ igba ti awọn obinrin ko ni le ṣe nnkan oṣu wọn mọ, eyii to tun n tumọ si pe wọn ko ni le loyun.
'Menopause' yii maa n waye ti obinrin ba ti n dagba, o si maa n bẹrẹ lati ọdun marundinlaadọta si ọdun marundinlọgọta.
O tun le waye nipa iṣẹ abẹ, eyi ti wọn n pe ni 'hysterectomy.'
Ti obinrin ko ba ri nnkan oṣu rẹ fun oṣu mejila gbako, o n tumọ si pe o ti wọ 'menopause' niyẹn.
Iye ọjọ ori ti obinrin ko fi ni ri nnkan oṣu rẹ mọ bẹrẹ lati ọdun mọkanlelaadọta, amọ o ṣeeṣe ki awọn obinrin kan ti ọjọ ori wọn ko tii wọ ọgbọn ọdun naa wọ menopause.