Ahmed Musa padà sí Kano Pillars, ó ní òun ṣetán láti rọ òjò góòlù lulẹ̀

Aworan Ahmed Musa

Oríṣun àwòrán, Ahmed Musa/Facebook

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Balogun ẹgbẹ agbabọọlu Super Eagles Naijiria, Ahmed Musa, to jẹ gbontarigi ẹlẹsẹ ayo ni aye ti n pariwo rẹ lori ayelujara nitori pe o pada wa sile wa maa gba bọọlu fun ẹgbẹ agbabọọlu Kano Pillars nipinlẹ Kano.

Kano Pillars n kopa ninu idije ere bọọlu Naijiria ti wọn n pe ni NPFL, ọpọ awọn ololufẹ ikọ agbabọọlu naa lo ti n gboriyin fun Musa lori bo ṣe gba goolu meji wọle nine ere bọọlu akọkọ rẹ fun Kano Pillars lati igba to ti pada sibẹ..

Ninu idije naa ni wọn ti figagbaga pẹlu ikọ agbabọọlu Sunshine Stars ni papa iṣere Muhammad Dikko to wa ni ipinlẹ Katsina lọjọ Aiku, ọjọ kẹfa, oṣu kọkanla, ọdun yii eyi to jẹ ifẹsẹwọnsẹ karun un ninu idije NPFL fun saa ọdun 2024/2025 yii.

Goolu meji ni Ahmed Musa gba wọle ninu ere bọọlu naa to si sọ pẹnaliti kan nu ni iṣeju aadọrin lẹyin ti idije naa bẹrẹ.

Kinni Ahmed Musa sọ?

Loju opo ayelujara Facebook rẹ ni Musa ti kọkọ sọrọ lẹyin ere bọọlu naa.

O ni “inu mi dun lati pada si ẹgbẹ agbabọọlu mi, Kano Pillars.

Mo dupẹ lọwọ awọn oṣiṣẹ ikọ agbabọọlu naa ati awọn akẹgbẹ mi fun anafaani ti wọn fun mi yii ati paapaa lọwọ gbogbo ẹyin ololufẹ mi to wa wo wa.

Ibẹrẹ ni goolu meji ti mo fi ṣide yii jẹ, ọpọ ṣi n bọ”

Igba kẹta ree ti Ahmed Musa maa gba bọọlu fun Kano Pillars, ọdun 2009 si 2010 ni Musa fi ba ikọ naa gba bọolu to si gba goolu mejidinlogun wọle ninu ifẹsẹwọnsẹ mẹẹdọgbọn to gba nibẹ ko to lọ silẹ okeere to ti kọkọ bẹrẹ pẹlu ikọ agbabọọlu VV Venlo ni Netherlands.

O pada sile lọdun 2021 lẹyin to kuro ni ikọ agbabọọlu Saudi Al Nassr nibi to ti kopa ninu ifẹsẹwọnsẹ mẹjọ ko to kuro nibẹ.

Aworan ikọ agbabọọlu Kano Pillars

Oríṣun àwòrán, Kano Pillars Fc / Facebook

Ọpọ lo ti n kọminu bayii lori ajọṣepọ to wa laarin Ahmed Musa ati Kano Pillars bo ya nkan to maa pẹ ni tabi nnkan ti ko nii pẹ.