Wọ́n dédé yìnbọn pa olóṣèlú ará India lórí ètò amóhùnmáwòrán, bó ṣe ṣẹlẹ̀ rèé

Oríṣun àwòrán, other
Oloṣelu tẹlẹ̀rí kan ti fara gba ọta ibọn to si gba ibẹ ku lori eto amohunmaworan to ti farahan pẹlu aburo rẹ.
Atiq Ahmed ni awọn ẹṣọ ọlọpaa to yii ka lasiko to n ba awọn oniroyin sọrọ lori amohunmaworan ni ilu Prayagraj nigba ti eeyan kan fa ibọn yọ lẹgbẹ ori rẹ.
Lẹ́yin ti iro ibọn jade lalẹ ọjọ Abamẹta ọhun ni awọn ọkunrin mẹta kan ti wọn ti n dibọn bii pe oniroyin niwọn juwọ lẹ fawọn ọlọpaa gẹgẹ bi ọdaran ti wọn si ko wọn lọ si atimọle.
Ọjọ melo kan sẹyin ni ọlọpaa kan ṣẹ yinbọn pa ọmọ oloṣelu naa.
Ki lo ti ṣẹlẹ́ ṣaaju?
Ọpọlọpọ ẹjọ lo ti wa nilẹ nipa Atiq Ahmed to fi mọ ẹsun ijinigbe, ipaniyan, ilọnilọwọgba ni wọn ti ka sii lọrun lati nnkan bii ogun ọdun bayii.
Koa ile ẹjọ ibilẹ kan ti ran oun ati eeyan meji kan lọ sẹwọn gbere ninu oṣu kẹta ọdun yii nitori ẹsun ijinigbe.
Ahmed naa ti figba kan pariwo sita ri pe awọn ọlọpaa n lepa ẹmi oun lati pa oun.
Fidio to wa lori ayelujara fihan bi Ahmed ati aburo, Ashraf rẹ ṣe n ba awọn oniroyin sọrọ pẹlu ẹwọn irin ti wọn ko si wọn lọwọ bi wọn ṣe n lọ fun ayẹwo ni ileewosan kan ki wọn to yinbọn pa awọn mejeji.
Ninu fidio naa to gba ori ayelujara atawọn tẹlifisan kan, awọn oniroyin n bere lọwọ Ahmed boya o lọ fun eto isinku ọmọ rẹ o si n da wọn lohun to si jẹ ọrọ ikẹhin rẹ pe:
“Wọn ko wa gbe wa lọ, torinaa a ko lọ.”
Awọn afurasi mẹtẹta ni wọn wa ọkada wọ ibi iṣẹlẹ naa gẹgẹ bi ọlọpaa ṣe sọ. Ọlọpaa kan ati oniroyin naa fori la iku nibẹ.
Awọn onimọ ti n bere pe bawo lo ṣe le ṣeeṣe ki wọn ri eeyan pa niwaju awọn oniroyin ati ọlọpaa.
Oniroyin BBC Hindi jabọ pe ilu naa wa ninu nnkan to jọ bii isede nigba ti iṣẹlẹ naa ṣẹlẹ.
Ahmed jẹ ogbologbo ninu ati oṣelu ati idigunjale. Oun ni wọn kọkọ fi ẹsun ipaniyan kan ninu ọdun 1979 to si di eeyan to ni nnkan ṣe pẹlu ilu Allahabab.
Pẹlu gbogbo akọsilẹ iwa ipa yii, o tun jawe olubori ninu idibo fun igba akọkọ gẹgẹ bi aṣofin lọdun 1989.








