Ọnà wo ní Israel fẹ́ gbé gbà pẹlú ikọlù orí ilẹ̀ tàwọn ọmọ ogun rẹ̀ fẹ́ ṣe sí Gaza?

Oríṣun àwòrán, EPA
- Author, By Jonathan Beale
- Role, Journalist
O jọ pe orileede Israel n se igbaradi lati da ọmọ ogun sita ti yoo kogun ori ilẹ ja Hamas ni Gaza.
Awọn ọmọ ologun laipẹ yi se ikilọ fun awọn eniyan to le ni miliọnu kan lagbegbe ariwa Gaza pe ki wọn sipo kuro lọ si Guusu ilu naa.
Bẹẹ naa si ni wọn ṣeto ẹgbẹgbẹrun awọn ọmọ ogun, awọn ọkọ ija ogun ati awọn ohun ija oloro si eti bebe agbegbe naa.
Ṣugbọn fifi awn ọmọ ogun ranṣẹ silu Gaza kii ṣe igbesẹ ti ko ni ewu ninu.
Iru bi wọn yoo ṣi ṣe ko ogun ori il yija Gaza ko ye ẹnikan ni pato-bawo ni ikogunja Gza yi yoo ṣe waye?
Titi diigba wo si ni wọn yoo fi ja ogun yi?
Nigba wo lo le waye?
Ipalẹmọ to ṣe pataki fun ikọlu si Gaza yi ti n bẹrẹ ni pẹrẹwu.
Ọgagun Amos Gilead ti kii ṣe ajoji si iru ikọlu bayii si Gaza sọ pe ohun tawọn ni lati kọkọ ṣe ni ki ijọba Israel fimọ ṣọkan ki awọn araalu baa le gbaruku ti wọn lori nkan to fẹ waye.
Laipẹ yi ni abẹwo awọn agba oloṣelu Amẹrika ati Yuroopu jẹ ki Israel ri atilẹyin lagbayebo ti lẹ jẹ pe atilẹyin yi le mẹhẹ bi ogun naa ba ṣe n pẹ si tawọn to n farakasa ba si ṣe n pọ si.
Iye awọn ọmọ Israel to ba farakasa ninu ogun yi naa yoo jẹ atọna bi ifarajin wọn ba ṣe lagabara si.
Ni ti iaplẹmọ awọn ọmọ ogun Israel, orileede naa ti ko awọn ọmọ ogun rẹ si ẹba ibode Gaza.
Awọn ọmọ ogun ẹgbẹrun lọna ọọdunrun kan ni wọn ti wa ni ṣẹpẹ pẹlu awọn mii ti wọn ya sọtọ ti awọn naa to ẹgbẹrun lọna ọgọjọ.

Oríṣun àwòrán, EPA
A ba awọn ọmọ ogun to ṣẹṣẹ wa kun awọn to wa nilẹ lagbegbe ariwa-o jọ pe ko ko ko lara wọn le tara wọn si wa lọna lati kopa ninuogun.
Nissim, ọkan lara wọn sọ pe Sri Lanka loun wa nigba ti ioyin iklu Hamas de si eti igbọ rẹ.
O loun ba baalu akọkọ pada si Israel lati lọ darapọ mọ ikọ rẹ.
''Ile wa ree. A nilati ja fun un ni.''
Ni ti Shuki, o fi iṣẹ onissowo rẹ to n ṣe ni kiakia ni.
O sọ pe ''Yoo wu wa ki alaafia wa''
Amọ o sọ pe ''o ṣeni laanu pe eleyi ko si.A nifẹ lati gbe ile aye yi tori naa a o kopa ninu ija yi ka baa le lẹtọ gbigbe ile aye.''
Awọn ọmọ ogun yi jọ pe ero ọkan wọn papọ ṣugbọn akoko n lọ pẹlu bi wọn ṣe n reti kawọn ọgagun paṣẹ ibẹrẹ ija fun wọn.
Bi wọn ba ṣe n pẹ si ni irẹwẹsi ọkan ṣeeṣe ko maa ba awọn to fẹ kopa ninu ogun yi.
Ikilọ ti Israel fi ṣọwọ pe kawọn ọmọ Gaza sa kuro lọ si agbegbe Guusu jẹ atọna ibi ti ọrọ yoo kangun si ninu ogun to sunmọ dẹdẹ yi.
Ipalẹmọ de ogun
Ohun ti Israel kọkọ ṣe ni pe wọn ri pe awọn di agbegbe wọn mu.
Wọ n tẹsiwaju lati pa tabi mu ki wọn si wadii ọrọ lẹnu eyikeyi ọmọ ogun Hamas ti ọwọ ba tẹ to sọda ibode lati wa pa eeyan to le ni ẹgbẹrun kan ti wọn si ji awọn to sunmọ aadọjọ gbe.
Israel ti n ṣe ikọlu si awọn ibudo ologun Hamas pẹlu ọkọ ija ofurufu ni lemọlemọ.
Laarin ọjọ mẹfa sẹyin o le ni ẹgbẹrun mẹfa ado oloro ti wọn sọ lu Gaza.
Ki a le mọ bi iye ado oloro yi ṣe pọ to lafiwe, ẹgbẹrun meje le ẹẹdẹgbẹrin ado oloro ni ọmọ ogun Nato ju ni gbogbo akoko ti ogun Libya fi waye lọdun 2011.
O sunmọ ẹgbẹrun meji eeyan to ti padanu ẹmi wọn ni Gaza lati igba ti wọn bẹrẹ si ni yin ado oloro yi.
Mẹnumọ ni wọn yoo ṣe igbaradi ati ipalẹmọ ikogunja Gaza yi amọ Israel ti n gbaradi lati ọpọ ọdun sẹyin.
Wọn ti n ṣe igbaradi fawọn ọmọ ogun wọn ni ibudo ijagun alaimọye miliọnu dọla to wa ni Guusu.
Gaza kekere lorukọ ti wọn pe ibudo ipalẹmọ ogun yi.
Ni aaye taa n wi yi, wọn n kọ wọn bi wọn ṣe le kopa ninu ogun laarin awọn ile to sunmọ ara wọn ati ilẹ ti wọn gbẹ labẹlẹ eyi ti wọn gbagbọ pe o le ni ẹgbẹrun kan iru rẹ ti Hamas ti gbẹ kalẹ.
Yaakov Katz, olootu agba nigba kan ri fun ileeṣẹ iroyin Jerusalem Post to si tun kọ ọpọ iwe nipa ọmọ ogun Israel sọ pe tori iru ogun bayii ni wọn fi ṣe agbekalẹ ileeṣẹ ologun Israel si awọn ẹka akọṣẹmọṣẹ.
O ni wọn yoo ṣamulo awọn onimọ ẹrọ pẹlu ọkọ katapila ti yoo maa run nkan lọ pẹlu awọn ọkọ ija ati ọmọ ogun ori ilẹ.
Aaye ijagun ati awọn oju ọna abẹlẹ ti Hamas gbẹ
Ọgagun Yaakov Amidror,adari ọmọ ogun IDF nigba kan ri to tun jẹ oludamọran aabo loun gba pe lootọ kikoju Hamas kii ṣe nkan to rọrun.
O ni Hamas yoo ti kẹ awọn ado oloro kaakiri abawọle awọn oju ọna ati kọrọkọrọ.
Israel lawọn gbagbọ pe Hamas ni ọmọ ogun to sunmọ ẹgbẹrun lọna ọgbọn ti wọn si ni nkan ija ogun bi ibọn,irinṣẹ ti wọn fi n yin ado oloro ati awọn irinṣẹ ija to n kọdi ado oloro bakan naa.
Wọn ni Russia jẹ orisun awọn nkan ija wọnyii.
Bẹẹ naa ni Hamas lawọn nkan ija ado oloro ti wọn ko pamọ lara elyi ti wọn n yin si Israel lọwọ.
Yaakov Katz sọ pe Hamas ti n peloo awọn dirooni aṣekupani atọwọda ti wọn.
O tun sọ pe wọn ni awọn irinṣẹ agbekọpa ti wọn le fi yin ado oloro amọ ọkọ ogun orilẹ bi tii Israel nikan ni wọn ko ni.
Amọ ohun to jẹ ipenija fun Israel ni ogun kọjusimi kọju si ẹ lawọn agbegbe ti o lero pupọ.
Israel lawọn to ṣa lẹṣa ti yoo kopa ninu ogun abẹlẹ to fi mọ awọn onimọ ẹrọ ti wọn pe orukọ wọn ni Yahalom, ati Oketz ti wọn mọ nipa fifi aja ba eeyan ja.
Ọgbẹni Katz sọ pe awọn ọmọ ogun Israeli yoo yago fun wiwọ inu awọn koto abẹlẹ ti Hamas gbẹ bi ko ba jẹ pe o di dandan.
Idi ni pe awọn ọmọ Hamas yoo mọ nipa wọn ju wọn lọ.
Kaka bẹ o ni awọn yoofi ado oloro di ẹnu ọna abawọle awọn koto yipa pẹlu ado oloro.
Kini yoo ṣẹlẹ sawọn ti Hamas jigbe?

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Awọn to wa ni ahamọ Hamas le fẹ jẹ ki ikogunja Gaza lori ilẹ ṣoro diẹ.
Ọgagun Gilead kopa ninu idunadura ti wọn fi tu ọmọ ogun Israel kan,Gilad Shalit, to wa ni ahamọ fọdun marun un silẹ.
Larin 2006 si 2011 ni wọn fi ji gbe.Ni ipari wọn fi ẹmi ọmọ ogun yi paarọ tawọn ẹgbẹrun kan ọmọ Palestine to wa ni ahamọ Israel.
Ọgagun Gilead sọ pe awọn ọmọ ogun yoo ni lati fi tawọn to wa ni ahamọ Hamas yi ṣe .
O ni ''bi a ko ba ṣe nkan to munadoko, o ṣeeṣe ka koju awọn ipenija mii to lagbara''
Amọ ṣa Ọgagun Amidror sọ pe an to wa ni ahamọ ko ni jẹ idiwọ tawọn ko fi ni gbe igbesẹ kankan.
O ni '' a o koju Hamas de opin ni. A o si ni lati wa awọn to wa ni ahamọ lasiko ta baa n jagun pẹlu Hamas''
Ki gaa n lero ọkan Israel?
Ni ṣoki, pipa Hamas rẹ ni o jẹ adisọkan Israel.
Ọgagun Gilead sọ pe erongba awọn kọja ṣiṣe iru ikọlu to waye tẹlẹ to ṣepe awọn kan fẹ fi dẹkun Hamas ni.
O ni lọtẹ yi,''a ni lati gbe igbesẹ to lagbar gaa an.''
O ni igbesẹ ologun to fẹsẹ mulẹ yoo jẹ bi ikilọ fawọn ọta mii lagbegbe awọn bi Hezbollah ati Iran.
Ọgbẹni Katz gbagbọ pe igbesẹ Israel yoo jẹ pẹlu ọpọ iwoye eleyi ti wọn yoo fi ri wi pe Hamas ko ni ribi kora jọ lati klu Israel lae mọ.
O ni Israel ''ko fẹ tun aaye gba ni Gaza t'awọn yoo si ni lati maa tọju awọn eeyan miliọnumeji to koju oro sii''.
Amọ awọn nkan to ṣẹlẹ ninu itan laipẹ fi han pe kii ṣe gbogbo igba lafojusun kikogun ja eeyan a maa lọ bi eeyan ba ṣe lero.
Koda a ri wi pe o maa n rẹ orileede to ni ikapa awọn ọmọ ogun to pọ.
Apẹrẹ kan taa ri tọka si ni ohun to ṣẹlẹ si Amẹrika to kogun ja Afghanistan ati omiran to waye laipẹ yi nigba ti Russia toun ti agbara rẹ ko ribi kapa Ukraine.












