Ekiti 2022: A ti ṣètò aàbò tó péye fún Olùdíje, Olùdìbò àti Oṣìṣẹ́ INEC ni ekiti- Kokumo

Àkọlé fídíò, Ekiti 2022: A ti ṣètò aàbò tó péye fún Olùdíje, Olùdìbò àti Oṣìṣẹ́ INEC ni ekiti- Kokumo

Aabo to daju wa fun gbogbo eeyan Ekiti titi dèyìn igba ti wọn ba kede ẹni to jawe olubori- Oga Olopaa Kokumo.

Gbogbo Abiyamọ, ẹ fa ọmọ yin leti ni Ekiti- Oga Olopaa Johnsoon Babatunde Kokumọ.

Oga agba Johnson Babatunde Kokumọ to jẹ adari gbogbo ikọ agbofinro to n mojuto eto idibo Ekiti lonii.

Johnson Babatunde Kokumo salaye pe eto aabo to peye ti wa fun awọn Oludije, Oludibo, Oṣiṣẹ eleto idibo INEC, ati awọn ara ilu Ekiti lapapọ.

O ni pe awọn yoo duro gbagi ni Ekiti titi deyin ti wọn ba kede eni to bori.