UK: Ọjọ́ kejilelogun, oṣù keje, ọdún 2019 ni wọ́n yóò ṣe ìkéde

Theresa May kọwe fipo rẹ̀ silẹ lọsẹ keji lẹyin to kede lati ṣe bẹẹ.
O fi iwe ikọsile naa ranṣẹ sawọn igbimọ Backbench 1922 gẹgẹ bi o ṣe fẹẹ.
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post
Awọn aṣoju mọkanla lati ẹgbẹ oṣelu Conservative nilẹ Gẹẹsi ni wọn jọ n gbero lati dupo yii.
Ojọ kejilelogun, oṣu keje, ọdun 2019 ni wọn yoo kéde ẹni ti yoo wọ bata ti Theresa May bọ silẹ yii.
Mọ síi nípa àwọn ti wọn n dupo Theresa May:
Sam Gyimah jẹ ọkan lara awọn mọkanla naa bo tilẹ jẹ pe iran rẹ tan mọ orilẹ-ede Ghana.
O ti sọju ninu ile igbimọ naa lati ọdun 2010. O kawe ni Ghana ati ni Uk ko to jẹ minista fun fasiti, ati minista fun ọrọ ile ewọn, ọrọ itọju awọn ọmọde ati bẹẹ bẹẹ lọ.
Bakan naa lo ti ba Adari David Cameron ṣiṣẹ bii akọwe agba to ṣee finutan.
Awọn mii ti wọn tun jọ fẹ wọ bata ti Theresa May bọ silẹ lataari ọrọ Brexit ni Dominic Rab.
Rab ti fero ọkan rẹ han lori ọrọ Brexit.
O ni oun a rii pé UK yọ kuro ni Brexit ko to di ọjọ kọkanlelọgbọn, oṣu kẹwaa, ọdun yii ti oun ba de ipo naa.
Michael Gove naa ti kede pe ipo naa wu oun ni UK.
Awọn mii ni Raab, Boris Johnson ti Donald Trump, aarẹ ilẹ̀ Amerika ni oun faramọ atwaọn miran.
Koko pataki to wa nibẹ ni pe ọpọ ninu wọn gba pe oorun to ran loke ṣi to aṣọ lati gbẹ lori ọrọ Brexit ko to di oṣu kẹwaa ọdun yii.
Wọn gba pe ohun ikunna nla ni ki ọrọ Brexit ma yanju.

















