Donald Trump: Mo dúpẹ́ lọ́wọ́ Jeff Sessions fún isẹ́ tó se lásìkò rẹ̀

Aarẹ Ilẹ Amẹrika, Donald Trump ti fọwọ osi juwe ile fun agbẹjọrọ agba ile naa, Jeff Sessions, lẹyin ti wọn pari idibo si Ile Igbimọ Asofin.
Trump lori itakun ikansiraẹni Twitter rẹ dupẹ lọwọ Arakunrin Sessions fun igba ati akoko rẹ pẹlu isejọba oun.
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post
Lọpọ igba ni aarẹ Trump ti bu ẹnu atẹ lu agbẹjọro agba lorilẹ-ede naa lẹyin to yọ ara rẹ kuro ninu iwadii nipa ẹsun ti wọn fikan orilẹ-ede Russia pe wọn ṣe magomago lasiko idibo sipo aarẹ lorilẹ-ede Amerika lọdun 2016.
Adari awọn oṣisẹ, Mattew Whitaker, ni yoo ṣe adele titi Aarẹ Trump yoo fi yan Agbẹjọrọ Agba tuntun.
Ẹgbẹ òṣèlú alátakò gba ilé aṣojú-ṣòfin lọ́wọ́ Trump
Ẹgbẹ oṣelu Democrats ni orilẹ-ede Amerika, ti gbo ewuro soju Aare Donald Trump ati ẹgbẹ oṣelu Republican, lẹyin ti wọn jawe olubori ninu idibo si Ile Igbimọ Asofin lorilẹede naa.
Jijawe olubori lati gba Ile Asofin lọwọ awọn Republican fun igba akọkọ laarin ọdun mẹjọ, yoo fun ẹgbẹ oselu alatako Democrats ni aaye lati sewadii Aare Donald finifini lori awọn ẹsun ti wọn fi kan an.

Oríṣun àwòrán, Reuters
Amọ, Aarẹ Trump ti ẹgbẹ oṣelu Republican lo si jawe olubori ni idibo si ipo Ile Igbimo Aṣofin Agba.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
Awọn obinrin wa lara awọn to jawe olubori lẹgbẹ oṣelu Democrats si Ile Igbimo Aṣofin kekere.
Awọn eniyan ri idibo to waye ni Ọjọ Iṣẹgun naa gẹgẹ bi eto lati mọ bi Aarẹ Trump ṣe gbajugbaja si laarin awọn ara ilẹ Amẹrika, bi o tilẹ jẹ wi pe o le ma dije dupo ni idibo sipo aarẹ lọdun 2020.
Ki idibo naa o to waye, ida ọgọrin ninu ọgọrun awọn ijoko ile aṣofin yii ni o jẹ pe awọn oloṣelu alawọ funfun ni wọn dii mu.

Oríṣun àwòrán, Getty Images
'Àdúrà nikálukú ń gbà pé kí Democrat wọlé'
Awọn ọmọ ilẹ Amẹrika kan ti wọn jẹ alawọdudu ni wọn salaye pe Aarẹ ilẹ Amẹrika Donald Trump n fi aye ni awọn lara lorilẹede naa.
Ọkan ninu wọn to ba BBC Yoruba sọrọ Fatima Gbenla sọ pe oju awọn ọmọ ilẹ Amẹrika ti wọn jẹ ọmọ ilẹ Afirika tabi alawọdudu n ri mọbo.

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Bẹẹ naa ni ẹlomiran to tun ba ile isẹ BBC sọrọ Sola Longe ni Aarẹ Trump ko ni le tẹsiwaju pẹlu igbesẹ rẹ lori ofin to ti pinnu fun awọn alejo ti ẹgbẹ oṣelu Democrat ba wọle ninu idibo ile aṣofin to waye.
Ninu idibo ile aṣofin apapọ orilẹ-ede Amẹrika to waye ni ọjọ kẹfa, oṣu kọkanla, awọn ọmọ orilẹ-ede Amẹrika yoo yan awọn ọmọ ile aṣoju ṣofin wọn, wọn o si tun yan mẹtalelọgbọn ninu ọgọrun un awọn aṣofin agba nibẹ pẹlu.
Ile aṣofin mejeeji yii ni o parapọ di ẹka aṣofin apapọ ni orilẹ-ede Amẹrika.
Lọwọ yii, ida ọgọrin ninu ọgọrun un awọn ijoko ile aṣofin yii ni o jẹ wi pe awọn oloṣelu alawọ funfun ni wọn dii mu.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
Gẹgẹ bi iwadii ijinlẹ kan ṣe fi idi rẹ mulẹ, awọn eeyan wọnyii ni wọn ko ida ọgọta ninu ọgọrun awọn eeyan to wa lorilẹ-ede Amẹrika.
Bi o tilẹ jẹ wi pe ilaji awọn eeyan ilẹ Amẹrika ni wọn jẹ obinrin, sibẹ, ida ogun ninu ọgọrun ni ipo oṣelu ti wọn di mu.
Awọn ẹya kekeke ti wọn tobi julọ-Hispanic, aṣia ati adulawọ amẹrika- pẹlu ko ri aaye to to ni ile igbimọ aṣofin yii.
Awọn obinrin ni Washington

Oríṣun àwòrán, Getty
Ni ọdun 1992, iye awọn obinrin to n kopa ninu oṣelu pọ sii, pẹlu didibo yan obirin mẹrinlelaadọta si ile aṣofin apapọ orilẹ-ede Amẹrika.
Eyi tumọ si afikun oni ida mọkandinlaadọrin si ti saa iṣejọba ti o ṣaaju wọn.
Fun idibo ọdun 2018 yii, iye awọn obinrin ti wọn n gbe apoti idibo pọ ni iye.
Aadọjọ ni awọn obinrin ti wọn n dije ninu idibo sile aṣofin apapọ lẹyin ti wọn ti yege ninu idibo abẹnu ninu ẹgbẹ oṣelu ẹnikọọkan wọn.
Awọn idena si kiko pa ninu idibo.

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ni ọdun 1965 ni ofin to de ẹtọ idibo waye labẹ ijọba aarẹ Lyndon Johnson, bẹẹni awọn atunṣe gbogbo lo ti de baa, lati fopin si iwa idẹyẹsi lorilẹ-ede naa, eleyi si ti mu ki iye awọn adulawọ Amẹrika to n kopa ninu idibo lorilẹ-ede Amẹrika o pọ sii.
Ṣaaju eyi, orisirisi iṣẹlẹ idẹyẹsi ati dide awọn oludije lati ẹya kekeke ni orilẹ-ede Amẹrika lọna lati mase lee du ipo n waye lọpọ yanturu.
Ni igba ti o di ọdun 1975 ti atunṣe waye si ofin ẹtọ oludibo ti anfani ati dibo si waye fun awọn ẹya kekeke.
Awọn ọmọ onilẹ Amẹrika ni ile aṣofin apapọ

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ko si aaye anfani ọmọ onilẹ fawọn ẹya ọmọ onilẹ ni ilẹ Amẹrika titi di ọdun 1924. Amọṣa, nigba naa gan, ko si aye fun wọn lati dibo nitori awọn ipinlẹ pupọ ni wọn ṣe ofin to fi ẹto idibo dun wọn.
Nibayii, iwadi ileeṣẹ kan to n wadi ijinlẹ lori ileegbimọ aṣofin apapọ ṣalaye pe, ko din ni mẹrin awọn ẹya ọmọ onilẹ ni ilẹ Amẹrika ti wọn ti dibo yan si ile igbimọ aṣofin apapọ orilẹede Amẹrika bayii, meji ninu wọn ni o wa ni ile aṣoju-ṣofin lọwọ bayii- Tom Cole, lati ẹya Chickasaw ni Oklahoma, ati Markwayne Mullin, ti ẹya Cherokee ni Oklahoma kan naa.
'Se nnkan yoo yatọ ni ọdun 2018?
Lootọ ni pe awọn obinrin ati awọn ẹya kekeke ni orilẹ-ede Amẹrika ti n pọ sii ni ile aṣofin apapọ orilẹ-ede Amẹrika. Amọṣa, akojọpọ awọn aṣofin ni ile aṣofin apapọ orilẹ-ede Amẹrika ko tii fi iye awọn eeyan to wa ninu rẹ han.


















