Èéfín gẹnẹratọ: Iléẹjọ́ ní kí ayálégbé san ₦2m owó ìtanràn

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ile ẹjọ kan ni agbegbe Ikẹja nipinlẹ Eko ti ni ki ayalegbe kan san miliọnu meji owo gba mabinu fun ayale ẹgbẹ rẹ nitori eefin ẹrọ amunawa.
Ọjọ Aje ni ile ẹjọ gbe idajọ kalẹ pe, ki ayalegbe naa san owo ọhun fun ayalegbe ẹgbẹ rẹ, Bunmi Ọdẹniyi, nitori pe eefin ẹrọ amunawa rẹ n wọ ile Ọdẹniyi, nile ti awọn mejeeji n gbe ni Gbagada, nilu Eko.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
Ile ẹjọ sọ pe ẹsun naa n bẹ labẹ abala ti wọn pe ni 'aikọbi ara si nkan' labẹ ofin orilẹede Naijiria. Ofin naa fihan pe, ojuṣe aigbọdọ ma se ni ki o maa ro eto idẹrun alajọgbepọ rẹ mọ ti ẹ.
Ẹjọ naa to ti wa nile ẹjọ lati ọdun 2015, ni wọn gbe idajọ rẹ kalẹ lọjọ kẹfa, oṣu Kọkanla,.

Oríṣun àwòrán, @HeyLagos
Ile ẹjọ sọ pe ki alajọgbelepọ Ọdẹniyi san miliọnu meji Naira fun ipalara, aisan, idinilọwọ pẹlu ariwo, ti ẹrọ amunawa rẹ ọhun fa fun ẹnikeji, to jẹ alabagbele rẹ.
Awọn ohun to yẹ ki o ṣe to ba n lo ẹrọ amunawa rẹ
Ko jẹ tuntun mọ pe ọpọlọpọ ọmọ Naijiria lo gbọkan le ẹrọ amunawa fun ipese ina ẹlẹtiriiki ninu ile ati ibi iṣẹ wọn
Bẹẹni kii si ṣe ẹẹkan tabi ẹẹmeji, ni iroyin ti gbe e pe, eefin ẹrọ amunawa ṣekupa mọlẹbi ni Naijiria
- Eefin ẹrọ amunawa ni eroja kan ti wọn n pe ni 'carbon monoxide' ninu, eyi to jẹ afẹfẹ to ni oro ninu, to si lee pa eeyan
- Oorun eroja naa ko ṣe e gbọ, nitori naa ti o ba ti n gboorun eefin ẹrọ amunawa rẹ, a jẹ wi pe eroja carbon monoxide lo n fin simu
- Ohun to daju, to si ṣe pataki ni pe ki gbogbo ẹni to n lo ẹrọ amunawa mọ ni pe, eefin to n jade lati ara ẹrọ amunawa le ṣekupani
- O ko gbọdọ gbe ẹrọ amunawa rẹ si ara ileti awọn eniyan n gbe
- Ẹrọ amunawa gbọdọ jinna si ibi ti ẹnu ilẹkun tabi ferese ba wa ni nkan ti ko din ni iwọn ẹsẹ bata ogun
- Ri i daju pe ọpa to n gbe eefin jade latara ẹrọ amunawa rẹ kọju si ibi ti afẹfẹ ti n fẹ
- Pa ẹrọ amunawa rẹ, ko si tutu daada ki o to rọ epo si i, nitori ti epo ba da si ori rẹ, o le gba ina
- Maa ranti nigba gbogbo pe eefin ẹrọ amunawa alagbagbepọ rẹ le le ṣe ipalara fun ọ, nitori na, ri i daju pe ibi ti o tọ ni alabagbepọ rẹ gbe ẹrọ amunawa rẹ si









