Paul Biya: Kìí ṣèpàdé pẹ̀lú àwọn mínísítà rẹ̀, ilé ìtura ní Switzerland ló ń gbé

Oríṣun àwòrán, AFP
- Author, Leocadia Bongben
- Role, BBC News Pidgin, Cameroon
Aarẹ orilẹede Cameroon, Paul Biya, yoo ṣe ibura wọle fun igba keje ni ọjọ Iṣẹgun, ọjọ kẹfa, oṣu Kọkanla.
Ọdun 1982 ni aarẹ Paul Biya gba ọpa asẹ lati maa dari orilẹ-ede Cameroon, o si jẹ ọkan lara awọn aarẹ to dagba julọ lori oye ni ilẹ Afrika.
Nigba to si jẹ pe saa keje lo fẹ se bayii lori aleefa, o yẹ kẹ mọ awọn ohun meje nipa aarẹ Biya, ti orilẹ-ede Cameroon naa.
1. O jẹ́ ọ̀kan lara awọn olórí ni Afrika to n gba owó ju lọ

Oríṣun àwòrán, NIC BOTHMA
Aarẹ Biya wa lara awọn aarẹ to n gbowo ju lọ ni Afrika. O ti ẹ ṣeeṣe ko jẹ oun lowo oṣu rẹ pọ ju. Iwe iroyin African Review sọ pe, Biya n gba ọtalelọọdunrun o din ẹyọkan miliọnu CFA francs, owo orilẹede Cameroon, ti afiwe rẹ jẹ ẹgbẹrun lọna ẹgbẹta o le mẹwa Dọla ($610,000) lọdọọdun.
2. Baba onile to n sun ita ni Biya

Oríṣun àwòrán, Intercontinental Hotel
Awọn kan maa n ṣapejuwe Aarẹ Biya gẹgẹ bi baba onile, ṣugbọn ti kan-in-kan-in ile rẹ kii ta nidi, nitori pe ọpọlọpọ akoko lo maa n wa ni awọn ile itura to gbayi, to si wọ́n pupọ ni orilẹede Switzerland.
O si maa n ko to ogoji eniyan dani lọ fun irinajo kọọkan to ba n lọ, wọn si le na to ẹgbẹrun mejidinlaadọta le ni ẹẹdẹgbẹta Dọla l'ọjọ kan.
Ajọ aladani kan tilẹ sọ pe o ti na to aadọrun biliọnu FCFA laarin ọdun 1982 si 2017.
3. Aarẹ Biya jẹ ọkan lara awọn aarẹ to dagba ju ni Afrika

Oríṣun àwòrán, Lintao Zhang
Aarẹ Biya bọ si ori aga iṣakoso l'ọjọ kẹfa, oṣu Kọkanla, ọdun 1982, lasiko ti Aarẹ Amadou Ahidjo gbe agbara iṣakoso le e lọwọ. Yoo si tun bura wọle fun saa ọlọdun meje mi i, eyi ti yoo mu ko pe ọdun marundinlogoji to ti wa nipo.
Biya ti pe ẹni ọdun marundinlaadọrun. Ilaji awọn ọmọ orilẹede Cameroon tilẹ sọ pe Biya lo ti wa ni ipo lati igba ti wọn ti bi wọn.
4. Igba meji lo ti ṣegbeyawo

Oríṣun àwòrán, CHRISTOPHE SIMON
Aarẹ Biya ti fi igba kan jẹ́ ọmọ ile ẹkọṣẹ alufaa Katoliiki, ko to di pe o fẹ iyawo rẹ akọkọ, ti ko bimọ fun un. Aṣa wọn si ni pe o le bimọ lati ara arabinrin iyawo rẹ.
Lẹyin ti Jean Irene Biya ku, ni aarẹ Biya fẹ Chantal, wọn si bi ọmọ meji. Chantel ti kọkọ bi ibeji fun ọkunrin kan.
5. Biya ko kuna ri ninu eto idibo aarẹ

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Aarẹ Biya kọkọ fi ẹyin Amadou Ahidjo janlẹ l'ọdun 1982. Lẹyin ọdun mẹwaa, o tun bori ni 1992, 1997, 2004 ati 2011. Bakan naa ni 2018, o bori pẹlu ibo ìdá mọkanlelaadọrin, botilẹ jẹ pe eniyan miliọnu meji ataabọ pere lo dibo ninu miliọnu mejilelogun to yẹ ko dibo.
6. Iwa jẹgudu-jẹra gbayi l'orilẹede naa

Oríṣun àwòrán, MARCO LONGARI
Cameroon ti gba ami ẹ̀yẹ fun iwa ibajẹ lẹẹmeji, kekere kọ si ni kiko owo ìlú jẹ lati igba ti Aarẹ Biya ti wa nipo fun ọdun marundinlogoji bayii. Cameroon lo wa ni ipo mẹrindinlaadọjọ ninu orilẹede mẹrindinlaadọsan to n hu iwa ijẹkujẹ.
7. Aarẹ Biya kii ṣe ipade pẹlu awọn minisita rẹ

Oríṣun àwòrán, ALEXIS HUGUET
Aarẹ Biya kii ṣe ipade pẹlu awọn ọmọ igbimọ iṣakoso ati minisita rẹ ni gbogbo igba, ayafi asiko to ba fẹ ẹ yan minisita sipo nikan.
Eyi si mu ki kaluku wọn maa ṣe boṣe wu wọn lẹnu iṣẹ. Ọdun 2015 ni Biya ti se ipade igbimọ alaṣẹ kẹhin, ko to o tun ṣe ni 2018. O tilẹ maa n gba iṣẹ́ lọwọ minisita ti ko ti ẹ ri soju ri.












