Nasarawa lecturer viral video: Ọlọ́pàá mú olùkọ́ fásitì Lafia tí òun àti ọmọ rẹ̀ já ọmọ obìnrin kàn sí ìhòhò

Olukọni ni Fasiti Lafia yi fi sisọọsi ya aṣọ ọmọbinrin Blessing

Oríṣun àwòrán, @Sanchezbig17

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 2

Ileeṣẹ ọlọpaa nipinlẹ Nassarawa ti mu olukọ fasiti ijọba apapọ Lafia kan ati ọmọ rẹ lori ẹsun pe wọn da bantẹ iya fun akẹkọọ obinrin kan ti wọn si tun ja si ihoho.

Alukoro ọlọpaa sọ fun BBC pe awọn ti mu ọmọwe Fred Ekpa Ayokhai to jẹ olukọni ni ẹka imọ itan ati ẹkọ ibaṣepọ agbaye to fi mọ ọmọ rẹ obinrin ẹni ọdun mejidinlogun Emmanuella Ayokhai.

Akẹkọọ fasiti Lafia yii ni ọmọ rẹ Emmanuella ati arabinrin Blessing ti wọn dijọ da ọwọ lu.

DSP Rahman Nansel sọ pe ọmọ olukọ naa kan to jẹ ọkunrin Praise to jẹ afurasi to lọwọ ninu lilu ọmọbinrin naa ati awọn mii ti na papa bora.

O fi kun pe iwadii n tẹsiwaju ti awọn si ti kọkọ fidi ọrọ mulẹ pe ija laarin awọn ọmọbinrin mejeeji yi lo da wahala silẹ.

O ni wọn n ba ara wọn ja lori ọkunrin kan ti wọn n du nọmba ẹrọ alagbeka rẹ mọ ara wọn lọwọ.

Aworan olukọ Fred Ayokhai nibi to ti n lu akẹkọọ pẹlu igi nla

Oríṣun àwòrán, @Sanchezbig17

Àkọlé àwòrán, Ọmọwe Fred Ekpa Ayokhai nibi to ti n fi igi lu arabinrin naa

Ohun to ṣẹlẹ ninu fọnran fidio naa

Ninu fnran fidio kan ti o gbode, niṣe la ri awọn eeyan kan to dawọjọlu arabinrin kan.Wọn lu, wọn ja si ihoho ti wọn si fi sisọọsi ja aṣọ rẹ ki wọn to le wọ igbo.

Iṣẹl yi baa ṣe gbọ bẹrẹ pẹlu fakinfa ko to di ranto laarin ọmọ obinrin yi ati ọrẹ rẹ lori ọrọ ọkunrin kan ati nọmba foonu rẹ ti o wa lori foonu obinrin ti wọn lu.

A ri ninu fido kan ti eeyan kan loju opo Twitter @Sanchezbig17 fi sita, a ri ibi ti awọn to n lu Blessing ti n fi igi nla lu.

Ọmọwe Fred Ekpa Ayokhai to pẹlu awọn to lu obinrin yi naa fi igi nlanla kan gba ọmọbinrin naa.

Ọlọpaa lawọn mu awọn afurasi meji lori iṣẹlẹ yi

Oríṣun àwòrán, @Sanchezbig17

Ninu awọn fidio mi taa ri, olukni ni fasiti Lafia yi lo sisọọsi lati fi ge aṣọ buba to wọ, to si ja si ihoho to tun bẹnu atẹ lu.

Wọn pada fi ọkọ wa lọ sinu igbo nibi ti wọn tẹsiwaju lati maa lu arabinrin naa.

Ileeṣẹ ọlọpaa ninu atẹjade sọ pe awọn ti mu awọn afurasi meji lori iṣẹlẹ yi tawọn si ti gbe ọkọ ti wọn fi gbe arabinrin naa lọ si inu igbo.

Skip X post
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: Third party content may contain adverts

End of X post