Discover Nigeria: Buhari ṣe ìfilọ́lẹ̀ ìwé tó sọ nípa ẹ̀wa Nàìjíríà ṣáájú ayẹyẹ òmìnira

Aarẹ Muhammadu Buhari

Oríṣun àwòrán, Femi Adesina

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 1

Yoruba bọ, wọn ni alara nii gb'ara ga, bi adiẹ ba fẹ wọle, a bẹrẹ.

Bi ayẹyẹ ọdun mọkanlelọgọta ti orilẹede Naijiria gba ominira ṣe ku ọjọ kan, Aarẹ Muhammadu Buhari yoo ṣe ifilọlẹ iwe kan to sọ nipa ẹwa, awọn ibi irinajo afẹ ati ohun manigbagbe ninu itan Naijiria.

Oludamọran fun aarẹ lori ọrọ iroyin, Femi Adesina to fi ọrọ yii lede ṣalaye pe akọwe iwe naa ni ''DISCOVER NIGERIA'' eleyi to tumọ si ṣe awari Naijiria.

Adesina ni ayafọto aarẹ Buhari, Bayo Omoboriowo, lo kọ iwe naa eyi to sọ nipa irinajo Naijiria lati igba ominira titi di akoko yii.

Iwe naa to ni ewe to din mẹjọ ni irinwo(392) lawọn eeyan ti sọ pe yoo wa lara awọn to lamilaaka julọ ninu lagbaaye.

Iwe yii sọ nipa awọn ọba alaye, oriṣiiriṣii ẹya, ilẹ oko Naijiria ati okun ti Eledua fi jinki Naijiria.

Omoboriowo ṣalaye pe iwe naa wa lara awọn eto lati fi ṣe ayẹyẹ ọgọta ọdun ominira orilẹede Naijiria.

Awọn ọdọ to le lọgọta ni wọn ṣiṣẹ pọ pẹlu Omoboriowo lori ati kọ iwe naa.

Ayẹyẹ ifilọlẹ iwe ọhun nile iṣẹ ijọba l'Abuja yoo tun ṣe afihan oriṣiiriṣii iṣẹ ọna lati ẹkun idibo mẹfa to wa ni Naijiria.

Koda oriṣiiriṣii ounjẹ awọn ẹya to wa ni Naijiria naa ko ni gbẹyin nibi ayẹyẹ ọhun.

Olori orilẹede Naijiria tẹlẹ. ajagun fẹhinti, Abdulsalami Abubakar, lo kọ ọrọ iṣaaju fun iwe naa.

Minisita eto iroyin ati ọrọ aṣa, Lai Mohammed lo kọ ọrọ ifihan fun iwe ọhun.

Koda, olori ologun Naijiria to tun jẹ aarẹ ologun orilẹede Naijiria tẹlẹ ri, Ibrahim Babangida naa ti ka iwe ọhun ti o si gboṣuba rabandẹ fawọn onkọwe Omoboriowo atawọn to ṣiṣẹ pọ pẹlu rẹ.