Saki Earth tremor: Ilẹ̀ mímì nílu Saki ti sọ àwọn olugbé ibẹ̀ sínú hílàhílo, ọ̀pọ̀ olùgbé ń sá fìlú sílẹ̀

ilu Saki

Inu ikayasoke ati ipaya lawọn eeyan ilu Saki ni ipinlẹ Ọyọ n gbe bayii lẹyin iṣẹlẹ ilẹ mimi to n waye nibẹ lati nnkan bi ọsẹ meji bayii.

Iṣẹlẹ naa to ti wa di lemọlemọ ti mu ki awọn olugbe ilu naa kan tilẹ di ẹru wọn gba ibomiran lọ.

Ni bi a ṣe n ko iroyin yii jọ, awọn alaṣẹ ajọ to n mojuto ọrọ oju ilẹ ati iwọn rẹ lorilẹede Naijiria, NGSA, Nigerian Geological Survey Agency ti fi awon akosomose ranse si ilu Saki lati le lọ ṣe kokari iṣẹlẹ naa.

Nigba ti ikọ BBC News Yoruba de ilu Ṣaki lati mọ bo ṣe nlọ nibẹ awon olugbe ilu naa ṣalaye pe ọpọ igba ni ilẹ naa yoo ṣa dede maa dun ti yoo si tun maa kun.

Awọn agbegbe bii Mọdina, Balako, Muslim Hospital, Isalẹ Adinni, Ero ọmọ, Ilupeju lọna Ọgbọrọ, irisad, Markaz ati bẹlbẹẹ lọ ni iṣẹlẹ ilẹ mimi naa ti saba n waye.