Coronavirus: A kò nílò láti ti àwọn ilé ìwé àti ilé ìjọsin wa pa- Minista ètò ìlera

Coronavirus

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán, A kò nílò láti ti àwọn ilé ìwé àti ilé ìjọsin wa pa- Minista ètò ìlera
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 5

Komiṣọnna fun eto ilera ni ipinlẹ Eko, Ojọgbọn Akin Abayomi ti kede iyasọtọ awọn mẹta miran lori iṣẹlẹ Coronavirus tuntun.

Lasiko ti Kọmiṣọnna n fidi ọrọ yii mulẹ lo sọ pe ijọba ti ya awọn eeyan yii sọtọ nile ifinipamọ to wa ni adugbo Yaba ni ipinlẹ Eko.

O ni ọkan awọn eniyan mẹta yii gba ipinlẹ Eko wọ Naijiria lọjọ Aje lẹyin ti wọn de lati orilẹ-ede France.

Skip X post
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: Third party content may contain adverts

End of X post

O ṣalaye pe ọkan ninu awọn meji to ku wọle lati England nigba ti ẹni kẹta wọn de lati China nibi ti arun Coronavirus yii pọ si.

Komisọnna Eko

Oríṣun àwòrán, @others

Àkọlé àwòrán, Ìpínlẹ̀ Eko kéde afurasí mẹ́ta míràn tó ṣeéṣe kó ni Coronavirus

Kò sí ìdí kankan fún wa láti ti ilé ìwé àti àwọn ilé ìjọsìn wa pa- Minista fun ètò ìlera ní Naijiria

Minista fun eto ilera ni Naijiria, Ọjọgbọn Osagie Ehanire lo fi ọrọ yii sita nilu Abuja pe ko si idi kankan fun Naijiria lati ti ile iwe ai awon ile ijọsin wa gbogbo pa nitori Coronavirus.

Minista ṣalye pe lọwọlọwọ yii, awọn mọkanlelogun ni wọn ti ya sọtọ niyara ifinipamọsi kaakiri ipinlẹ mẹrin ti wọn ti furasi iṣẹlẹ ọhun.

Ipinlẹ Eko, Ogun, Abuja ati Kano ni wọn ti kede pe awọn afurasi naa wa ṣugbọn ko tii si ẹni ti wọn ri to ti ni arun Coronavirus ni pato ni Naijiria.

Ojọgbọn Osagie fidiẹ mulẹ pe awọn eniyan marundinlọgọta o ba arinrinajo ara Italy naa rin ni wọn ti n ṣe ayẹwo fun laisko yii.

O ni awọn n ṣiṣẹ papọ pẹlu awọn aṣọbode ati ọmọ ogun ori omi lati tubọ maa ṣe ayẹwo ni kikun lori awọn to n wọle si Naijiria bayii.

Àkọlé fídíò, Ara: Láti kékeré ni mo ti ń lu ìlú pẹ̀lú ayọ̀

Kini o ti ṣẹlẹ ni Ghana nipa Coronavirus?

Ṣé àwọn òṣìṣẹ́ elétò ìlera Ghana yóò ya Aarẹ Akufo-Addo sọ́tọ̀ lẹ́yìn tó dé láti ilẹ́ Yúròòpù?

Coronavirus: Ààrẹ Ghana lọ sílẹ̀ Yúróópò fún ọjọ́ méjìlá níbití àrùn náà wà.

Ras Mubarak tó n ṣojú ẹkùn Kumbungu nílé àṣòfin àgbà ni Ghana n béèrè bóyá wọn yóò fí Aarẹ Akufo-Addo sí àhámọ́ lọ́tọ̀.

Aare Akufo-Addo

Oríṣun àwòrán, Office of the Ghana president

Àkọlé àwòrán, Kini o maa ṣẹlẹ̀ sí Aarẹ Akufo-Addo?

Lori iṣẹlẹ Corona Virus yii naa ni ibeere gbankọgbi ti n jade ni orilẹ-ede Ghana.

Ọgbẹni Mubarak to n ṣoju ẹkun Kumbungu nile aṣofin agba ni Ghana lo ṣide eto ipade naa pẹlu ibeere nla yii.

Mubarak beere lọwọ awọn oṣiṣẹ eleto ilera ilẹ Ghana boya wọn maa gbe igbesẹ lati ya Aarẹ Akufo-Addo to ṣẹṣẹ rin irinajo de lati ilẹ Yuroopu sọtọ ni iyara ahamọ tabi bẹẹ kọ.

O ni Mongila ati Aarẹ Dema naa gbe iru igbesẹ iayraẹnisọtọ yii nitori Arun COVID-19 to gbode kan yii.

Ọjọ mejila ni Aarẹ Akufo-Addo fi rin irinajo abẹwo si ilẹ Yuroopu pẹlu awọn mẹwaa ninu oṣiṣẹ ileeṣẹ Aarẹ Ghana.

Iroyin ni wọn de ọdọ Aarẹ Norway nibi ti eniyan mẹta ti lugbadi arun Coronavirus ti wọn si ti fi eniyan aadọta pamọ fun ayẹwo.

Ibẹru ohun ti arun CoronaVirus yii le bi to ba bẹ silẹ ni Ghana lo n jẹ ki awọn eeyan kan beere pe ki wọn fi Aarẹ Akufo-Addo pamọ bo ti yẹ.

Àkọlé fídíò, Obasanjo: Àwọn èèyàn ìpínlẹ̀ Ogun ní iṣẹ́ ṣì pọ̀ fún Ọbasanjọ láti ṣe fún mẹ̀kúnù Nàìjírìà

Háà, Coronavirus ba ọjọ́ ìbí mi jẹ́ tán, díẹ̀ ló kù, mo yára ṣàtúnṣe sí i - Obasanjo

Ààrẹ Naijiria àná, Olusegun Obasanjo ti ní àrun Coronavirus ló jẹ́ kí àtúnṣe débá ètò ayẹyẹ ọjọ́ ìbí rẹ̀ tó wáyé ní Abeokuta.

Obasanjo ati iyawo rẹ pẹlu awọn eeyan miran n ge akara oyinbo

Aarẹ orilẹ-ede Naijiria tẹlẹ, oloye Olusegun Obasanjo ti sọ pe itankalẹ arun Coronavirus lo mu ki oun ṣe atunṣe si bi oun ṣe fẹ ki ayẹyẹ ọjọ ibi oun waye.

Obasanjo salaye bẹẹ nigba to n ba awọn eeyan sọrọ nibi ayẹyẹ ọdun kẹtalelọgọrin rẹ nilẹ alaye, eyi to waye nilu Abeokuta.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Obasanjo ni awọn eeyan jankan ti oun fiwe pe lati awon orilẹ-ede miran lagbaye wa sibi ayẹyẹ naa, bii aarẹ orilẹ-ede Sierra Leone tẹlẹ, Bai Koroma, aarẹ Liberia ana Ellen Johnson-Sirleaf, atawọn mii ni ko lee wa sibi ayẹyẹ ọhun, nitori ibẹru arun Coronavirus.

Awọn alejo nibi ọjọ ibi Obasanjo

O ṣalaye pe "Lara awọn eto ti a pinnu lati ṣe ni lati lo ọjọ Isẹgun ati Ọjọru lati ṣagbeyẹwo bi awọn eeyan yii ṣe de ipo giga ti wọn wa, ati awọn ẹkọ ti a lee kọ lara wọn, ṣugbọn a ni lati gbe aba naa ti sẹgbẹ kan nitori ibẹru arun Coronavirus to n ja nilẹ."

Baba tẹ siwaju pe "Mo lero pe to ba di ọjọ iwaju, aye maa wa fun wa lati ṣeto ọhun nitori ọpọ nnkan la lee kọ lati ara wọn nipa awọn aṣeyọri ti wọn ti gbe ṣe, ati bi wọn ṣe ṣe."

Obasanjo ati Olagunsoye Oyinlola

Obasanjọ sọ pe ara eto ayẹyẹ ọjọ ibi naa ni lati ṣapero pẹlu awọn olori lati Asia, lati mọ aṣiri bi wọn ṣe goke agba lawujọ agbaye ati ẹkọ ti ilẹ adulawọ le kọ lara wọn.

O ni ọrọ aje orilẹ-ede Malaysia buru ju ti Naijiria lọ lasiko ta gba ominira lọdun 1960, bẹe naa ni South Korea ati Vietnam, ṣugbọn ni bayii, ọrọ aje awọn orilẹede naa ti ṣenu ire ju ti Naijira lọ, leyi to tumọ si pe, ọpọ nnkan ni Naijiria le kọ lara wọn.

Awọn alejo nibi ọjọ ibi Obasanjo

Ninu ọrọ rẹ, Gomina ipinlẹ Ogun, Dapo Abiodun sọ pe, awokọṣe nla ni Obasano jẹ lawujọ awọn oloṣelu ni Naijira ati kaakiri agabye.

O ni ti kii ba ṣe nitori Obasanjo ni, ki ba ma ti si ilu Owu ninu maapu orilẹ-ede Naijira.

Gomina ipinlẹ osun tẹlẹ, Olagunsoye Oyinlola naa sọrọ nipa Obasanjo, o ni baba rere ti eeyan le ṣawokọṣe rẹ gẹgẹ bi aṣaju rere ni Obasanjọ.

Oyinlola ni baba Obasanjo ni oun n wo niwaju, ti oun si mu bii baba ninu oṣelu ni Naijiria.

Lara awọn eeyan jankan to ba oloye Obasanjo ṣayẹyẹ ọjọ ibi rẹ naa ni, gomina ipinlẹ Ogun, Dapo Abiodun, gomina ana nipinlẹ Osun, Olagunsoye Oyinlola, Sẹnatọ ana, Florence Ita Giwa, onimọ nipa ọrọ aje, Nike Akande, atawọn eeyan nla miran.

Àkọlé fídíò, Xenophobia: Naijiria á kọ́kọ́ pèsè ọ̀nà láti bá ẹbí sọ̀rọ̀ fún wọn