Champions league: Chelsea gbélé fọrùn rọ́ ní Stamford Bridge, àwìn ni Valencia fi ṣẹ Lampard lọ́wọ́

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ẹgbẹ agbabọọlu Chelsea joye gbele forunrọ lalẹ ọjọ iṣẹgun nigba ti wọn gbalejo ẹgbẹ agbabọọlu Valencia ni idije Champions league.
Chelsea yoo maa pada si agbami bọọlu Champions league lẹyin ti wọn fi saa ọdun to kọja gba bọọlu ni agbami Europa. Amọṣa ipadabọ naa ko so eso rere ninu ifẹsẹwọnsẹ akọkọ ti wọn gba.
- Tani yóò gba ife ẹ̀yẹ UEFA Champions League ti saa yi?
- Watford da iyanrìn sínúu gaàrí Arsenal
- Òfò ṣ'ẹ̀dá: Ẹ̀fọn Norwich já bàálùu Man City
- Ronaldo, Messi ẹ yàgò lọnà fagbábọ́ọ̀lù Nàìjíríà tó n gbowò julọ!
- Tammy Abraham dáná sun Wolves, ni Twitter bá ń lọgun rẹ̀ tan-tan
- Egbé agbábọọlù Super Eagles gbàgbé ohun eèlò wọn - Ọlajiire
Bi o tilẹ jẹ wi pe ọdẹdẹ Chelsea ni Stamford Bridge ni ifẹsẹwọnsẹ naa ti waye, ko gbe Tammy Abraham atawọn ọmọ ikọ Frank Lampard yooku.
Rodrigo, ọmọ Valencia lo da okuta si gaari Lampard ninu ifẹsẹwọnsẹ rẹ akọkọ ni idije Champions league gẹgẹ bii olukọni Chelsea.

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Iṣẹju kẹrinlelaadọrin ni ifẹsẹwọnsẹ naa wa nigba ti Rodrigo fi gba bọọlu sinu awọn Chelsea.
Eyi ti ko ba tun duro gẹgẹ bii itunu fun Chelsea ni igba ti alamojuto ere naa fun fere fun pẹnariti, iyẹn gbe e silẹ ko gba a si sawọn ṣugbọn igbo rere ni Barkley agbabọọlu Chelsea to gba a gba a si.








