Adewale Adeyemo: Òun ni wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ yàn sípò ààrẹ fún àjọ Obama Foundation

Adewale Adeyemo

Oríṣun àwòrán, @tvnigerian

Adewale Adeyẹmọ tii se ọmọ Yoruba ni wọn ti kede bii aarẹ fun ajọ alaanu kan ti aarẹ ana nilẹ Amẹrika, Barrack Obama da silẹ, ti wọn pe ni Obama Foundation.

Adeyẹmọ, ti gbogbo eeyan mọ si Willy, jẹ ẹni ọdun mẹrinlelọgbọn, oun si ni yoo maa se akoso ojuse ati isọwọ sisẹ ajọ naa lati igba de igba, ti yoo si maa ri si amusẹ awọn afojusun ajọ ọhun.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Nigba to n kede Adeyẹmọ bii aarẹ fun ajọ naa, ọkan lara awọn oludari ajọ ajọ alaanu Obama, Martin Nesbitt salaye pe Adeyẹmọ ni ẹni to tọ lati gba ipo naa, ika to tọ si ni awọn fi re imu pẹlu iyansipo rẹ ọhun.

"Ta ba wo iriri to ni lẹnu isẹ ọba ati ti aladani, ati bo se fi tọkan tara sisẹ fun aarẹ tẹlẹ, Barrack Obama, Adeyẹmọ nikan lo kunju osunwọn lati se amusẹ awọn afojusun ajọ yii, ti yoo fi de ibi giga.

Adewale Adeyemo

Oríṣun àwòrán, @tvnigerian

Adeyẹmọ lo ti sisẹ saaju gẹgẹ bii oludamọran fun ijọba aarẹ Obama lori eto ọrọ aje lọdun 2015, ti ojuse rẹ nigba naa si jẹ sise akoso awọn ilana to jẹ mọ eto ẹnawo, okoowo ati idokowo, ohun amusagbara ati ọrọ to jẹ mọ ayika.

Awọn obi Adewale Adeyẹmọ la gbọ pe wọn wa jijẹ mimu lọ silẹ Amẹrika lati orilẹede Naijiria.