Issa Aremu ṣàlàyé kíkún nípa èròńgbà ẹgbẹ́ Labour to bá jáde

Àkọlé fídíò, Issa Aremu: ṣàlàyé kíkún nípa èròńgbà ẹgbẹ́ Labour to bá jáde

O ṣakawe nipa àwọn agba oloṣelu ati iṣẹ wọn fun BBC Yoruba lasiko ifọrọwanilẹnuwo naa.

Issa Arẹmu ti figba kan jẹ igbakeji aarẹ ẹgbẹ awọn oṣiṣẹ ti a mọ si Nigeria Labour Congress.

O n dije dupo gomin alabẹ ẹgbẹ oṣelu Labour Party ni Kwara.

Bi ọmọ kò bá ba itan, o di dandan kó ba àrọ́bá to jẹ́ baba ìtàn, Issa Arẹmu ṣalaye fun BBC pe oloṣelu to fẹ ṣaṣeyọri gbọdọ ṣetan lati sin awọn eniyan rẹ ni.

O fi Oloye Ọbafẹmi Awolowọ ati Saudana Sokoto ṣe akawe awọn oloṣelu ti ipa wọn ko le parẹ lai.

Issa Arẹmu ni ẹni to ba laya lo n dije dupo.

O mẹnuba gbogbo nkan ti oun ati ẹgbẹ rẹ ni lọkan lati ṣe fun awọn eniyan ipinlẹ Kwara ti oun ba wọle.