YK Abass, Sumaila Aderemi Jimoh: Kí ló ń ṣẹlẹ̀ nípa oyè 'Babalọja- General'ní ìpínlẹ̀ Oyo?

Awon ti ọrọ kan

Oríṣun àwòrán, Others

Ki lo n sẹlẹ nipa ọrọ oye 'Babaloja-General' n'ipinlẹ Ọyọ?

Eyi ni ibeere ti ọpọ n beere nipa ohun to n ṣẹlẹ bayii nipinle Oyo.

L'aipẹ yii ni Gomina ipinlẹ Ọyọ, Onimọẹrọ Ṣeyi Makinde kede Alhaji Yekini Abass gẹgẹ bii Babaloja fun gbogbo ipinlẹ Ọyọ.

Ọrọ oye naa ti da ọpọlọpọ awuyewuye silẹ saaju asiko yii ki Gomina to kede Babaloja tuntun.

Ninu ọrọ ti o fi lede lẹyin ikede naa, ẹni ti awọn eeyan mọ tẹlẹri gẹgẹ bii Babaloja gbogbo ipinlẹ Ọyọ, Alhaji Sunmaila Ad­eremi Jimoh ṣe alaye wi pe igbesẹ ti Makinde gbe lodi si idajọ ile ẹjọ lori ọrọ oye 'Babaloja-General'.

Jimoh ni agbara lati yan Babaloja fun gbogbo ipinlẹ Ọyọ ko si lọwọ ẹka ijọba kankan, yala lọwọ awọn alakoso ipinlẹ tabi awọn amofin, bikoṣe lọwọ gbogbo awọn ontaja to n bẹ n'ipinlẹ naa.

Gẹgẹ bi o ṣe sọ:

"Ejọ ti ile ẹjọ giga ipinlẹ Ọyọ da tako Alhaji Yekini Abass nibi ti ile ẹjọ naa ti fi ofin dee wi pe ki o dẹkun ati maa pe ara rẹ ni Babaloja gbogbo ipinlẹ Ọyọ ṣi fi idi mulẹ, nitori pe ile ẹjọ kankan ko tii tako aṣẹ naa".

Àkọlé fídíò, Shuahib Afolabi Salisu: Òótọ́ ni mo súnmọ́ Gómìnà ṣùgbọ́n mo kúnjú òṣùwọ̀n ni mo ṣe gba

Jimoh fi kun ọrọ rẹ wi pe ko si nnkan to jẹ tuntun ninu ikede ti ijoba ipinlẹ Ọyọ ṣe, paapaa julọ "nitori pe awọn eeyan ti kii ṣe oloootọ lo n ṣoju fun ijọba naa, ti wọn ko si ni ibọwọ fun ofin orilẹede Naijiria".

"A o fi ọwọ ofin mu ọrọ naa, Gomina yoo si mọ eyii tii se otitọ".

Àkọlé fídíò, Adewole Adebayo, Olùdíje sípò Aàrẹ lẹ́gbẹ́ SDP: Mo faramọ́ ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ láti mójútó aàb

Alhaji Ibrahim tẹsiwaju wi pe gbogbo igbiyanju lati da oju ilana to n ṣe anfani fun awọn ontaja ipinlẹ Ọyọ ru ni yoo re okun igbagbe ti gbogbo madaru yoo si ja si asan.

Àkọlé fídíò, Kwara Kidnap: N20 mílíọ̀nù ni wan kọ́kọ́ bèèrè fún, mo ta mọ́tò, mo fi ìwé ilé lọ yáwó- Lu

O ni, "ẹgbẹ ontaja ni wa, ẹgbẹ wa si forukọ silẹ labẹ ileeṣẹ ijọba to n mojuto idasilẹ ileeṣẹ and karakata.

A kii se ileeṣẹ ijọba, bẹẹ sini aṣoju ijọba kankan ko lẹtọ lati lati da si ọrọ bi a ṣe n yan Babaloja fun gbogbo ipinlẹ Ọyọ".

Àkọlé fídíò, Lukman Oyebisi Ilaka: Kò yẹ kó sí túlààsí, ìjà tàbí dídáná sunlé ara ẹni nítorí ibò

Jimoh ni ẹnikẹni ti idajọ ile ẹjọ ba ru loju, ki a gba ile ẹjọ lọ ki o si lọ beere alaye.