Wo bí Sunday Orimola ṣe gba ikú ẹranko kú ní Ifon ni Ondo lórí ọ̀nà àtijẹ
Ọjọ kẹtalelogun, oṣu keji, ọdun yii lo mu Sunday ọkọ mi dero ọrun lẹnu iṣẹ rẹ- Folakemi
Kayeefi BBC losu yii jẹ ti Oloogbe Sunday ẹni ọdun mejilelaadọta ti awọn fijilante ṣeeṣi yinbọn pa ni Omi Alafaa ni Ifọn ni ijọba ibilẹ Ọsẹ nipinlẹ Ondo.
Sunday jẹ akọṣẹmọṣẹ to n tun ohun gbogbo to n lo ina mọnamọna ṣe, o dẹ tun maa n fa ina sile tuntun kaakiri gẹgẹ bii ọna ati jẹ atimu.
- "Mi ò ní wọ Uber mọ́ tí wọ́n bá leè fi owó lée nítorí àfikún owó orí tí Sanwo Olu ṣe"
- Abọ́ fífọ̀ àti ilẹ̀ ọkọ̀ ojú omi ní gbígbá ní mó fi kọ́kọ́ bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́- Victor Agunbiade
- Àwọn nkan tó yẹ kí o mọ̀ nípa ṣíṣe ìṣirò àsìkò tí o bá n yé ẹyin
- Wo bí o ṣe le fi ẹjọ́ sun àjọ FCCPC tí o bá ra ọjà tó ti 'expire'
Iṣẹ akanṣẹ SUBEB ti wọn pee si lo sọ ọ di ero ọrun ni Ondo nigba to lọ yagbẹ laarin oru ti awọn fijilante si ni wọn ṣeeṣi yinbọn fun un.
Aṣẹ lati kọkọ lọ gba iwe lọdọ awọn Ọlọpaa ṣaaju itọju sunday ati aitete ri mọto to maa gbe e lo sile iwosan naa pẹlu ohun to jẹ ko doloogbe.
Gbogbo asiko ti wọn fi n ṣe eyi lati abule lọ si Ifọn, lọ si Ondo, lọ si Akurẹ kun ẹjẹ to n danu lejika Sunday nibi ti ibọn fijilante ti ba a.
- Wo nkan tó yẹ kí o mọ̀ nípa Tolanibaj, Wathoni àti Brighto ni wọ́n lé kúrò ni BbNaija l'ọ́sẹ̀ yìí
- Ọ̀fẹ́ ni China yóò kọ́ fásítì $50M ètò ìrìnnà sí Daura ìlú Ààrẹ Buhari- Amaechi
- Rabiu Yusuf, ìgbákejì ọ̀gá àgbà ọlọ́pàá Nàìjíríà (AIG) lẹ́kùn Katsina jáde láyé
- Wo ọ̀rọ̀ tí gbogbo agbàyé fẹ́ràn jùlọ lójú òpó Twitter
BBC ba awọn olugbe abule naa ti ọrọ ṣoju wọn sọrọ ilẹ kun.
Oba Olufọn ti ilu Ifọn naa ṣalaye pe nitori awọn darandaran Fulani to n ji eniyan gbe ni agbegbe naa ni wọn ṣe bẹrẹ fijilante ṣugbọn o ga ni
A fi ki Ọlọrun tu iyawo rẹ Folakemi Orimọla ati ọmọ kan ti Sunday Orimọla fi silẹ ninu ki onikaluku ma si rin arinfẹsẹ si lẹnu iṣẹ oojọ wa.

