Arsena:O kù diẹ̀ ki Aubameyang fẹnu ọ̀rọ̀ jóna lóri àdéhùn ọgọ́ta mílíọ́nù pọ́ùn

Pierre-Emerick Aubameyang

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán, Arsenal n foju sọ́na lati fi Aubameyang rọ́po Alexis Sanchez

Arsenal ti sún mọ́ bèbè àti fẹnu ọ̀rọ̀ jóná lóri àti buwọ́lu gbígba Pierre-Emerick Aubameyang kúro ní Borussia Dortmund pẹ̀lú ọgọ̀ta mílíọ́nu pọhun.

Ṣugbọn wọn o ni buwọ́lu igbesẹ asipo-rọpo naa titi ti Dortmund yòó fi ni arọ́po mí ì, yálà Olivier Giroud láti inú ikọ̀ Arsenal tàbí ẹlomìí nínú àwọn tí wọ́n fi orúkọ wọn sílẹ̀. .

Ẹ̀ẹ̀meji ọ̀tọ̀ọ́tọ̀ ni Arsenal ti ṣe idunadura lori atamatase ọ̀hun ti Dortmund kọ̀ silẹ̀.

Aubameyang, ẹni ọdún mejìdinlọ́gbọ̀n bẹ̀rẹ̀ pẹ̀lu Dortmund fún ìgbà àkọ́kọ́ lọ́jọ́ kẹrìndínlọ́gbọ̀n oṣù kejìlá.

Dortmund ní àwọn ti ṣetán láti tà á "bí àwọn ìlànà kan bá jẹ́ títẹ̀ le".

Pierre-Emerick Aubameyang ninu asọ Borussia Dortmund

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ikọ̀ nàá to n kopa ninu idije Bundesliga kọ aadọta miliọnu Euro ti Arsenal gbe kalẹ̀ lọ́jọ́ru to kọja.

Wọn fun Aubameyang ni iwe lọ gbele ẹ, ti ko si le e kopa ninu ifẹsẹ̀wọnsẹ̀ ti wọn ni pẹlu Wolfsburg nitori pe o pa ipade ẹgbẹ agbabọọlu naa jẹ lọ́sẹ̀ meji sẹ́yin.

Ọmọ orileede Gabon ọhun ni wọn tun yọ orukọ rẹ̀ kuro lara ikọ̀ to kopa ninu ifẹsẹ̀wọnsẹ̀ wọ́n to waye ní Hertha Berlin lopin ọ̀sẹ̀ to kọja nitori pe erongba awọn alasẹ ẹgbẹ́ agbabọọlu naa ni pe ko fọkan si nnkan toun se bose tọ̀, sugbọn o kopa fun aadọrun isẹ́ju ninu idije ti wọn ti ta ọ̀mì pẹ̀lu Freiburg.

Oludari ere idaraya ikọ Dortmund, Michael Zorc ninu ọ̀rọ̀ to sọ fun ileesẹ amohun-maworan orileede Germany ni:

''Ati setan fun aṣipo-rọpo ti awọn ilana kan ba fi jẹ́ titẹ̀le."

''Erongba wa o jẹ nnkan to pamọ́. Arsenal ti gbe orisirisi igbesẹ̀ sugbọ́n gbogbo rẹ̀ la kọ̀ jalẹ̀ titi di asiko yìí.

Pierre-Emerick Aubameyang lori papa

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán, Arsenal n foju sọ́na lati fi Aubameyang rọ́po Alexis Sanchez to darapọ̀ mọ́ Manchester United

Arsenal n foju sọ́na lati fi Aubameyang rọ́po Alexis Sanchez to darapọ̀ mọ́ Manchester United ninu osu yìí ninu igbesẹ̀ pasi-paarọ̀ ti wọ́n se láàrin òun àti Henrihk Mkhitaryan.