Nigeria Senate: Sanwó ìtúsílẹ̀ fún àjínígbé, kí ó lọ ẹ̀wọ̀n ọdún mẹ́ẹ̀dógún-Ilé ìgbìmọ̀ asòfin

Sanwó ìtúsílẹ̀ fún àjínígbé kí ó lọ ẹ̀wọ̀n ọdún mẹ́ẹ̀dógún

Oríṣun àwòrán, Senate

Ilé ìgbìmọ̀ aṣòfin àgbà Nàìjíríà ń gbèrò láti gbé òfin ti yóò dena sísàn owó ìtúsílẹ̀ fún àwọn ajínigbé ní Nàìjíríà.

Abádòfin ti wan pe àkọlé rẹ̀ ni ìdènà ìwà ìjínígbé ti ọdún 2021 The T errorism Prevention (Amendment) Bill, 2021, èyí si ti lọ siwajú ilé fún kíkà ni ẹ̀ẹ̀kejì lásìkò ìjòkó ilé lónìí.

Sẹnatọ Ezenwa Fracis Onyewuchi to sonigbọ̀wọ́ àbádòfin náà sàlàyé pé àbádofin ọ̀hun ni láti ṣe àtúṣe si òfin idènà ìjánigbé ti ọdún 2013 lati fofinde sísan owó ìtúsílẹ̀ fún àwọn ajínigbé.

Gẹ́gẹ́ bi Onyebuchi ṣe sọ abádòfin naa yóò mú àyípadà bá ipele kẹrinla òfin to wà nílẹ̀ tẹ́lẹ̀, ó kà báyìí pé; 'ẹnikẹ́ni to bá san owó tabí fún ẹnikẹ́ni lówó, tàbí tó pàdí àpòpọ̀ ma ẹnikẹ́ni, bi ajínígbé, agbésùmọ̀mi tàbi gba owó lórúkọ wọn fún ìtúsílẹ̀ jẹ́bi ọ̀daran yóò si lọ si ẹwọn ọdún mẹ́ẹ̀dógún.

Ó ké gbàjarè pé ọ̀rs ìjinígbé ni Nàìjíríà tí kọ sísọ ó sì ti dí iṣẹ́ tó lérè lórí púpọ̀ fún àwọn ọ̀bàyéjẹ́ ni Nàìjíríà.

Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé , ó sàlàyé pé nkan to fa irú ìwà báyìí kò ju ti àìríṣẹ́ ṣe ọ̀ps àwọn ọ̀dọ́, òsì, ẹ̀sin, òṣèlú, òfin ti ko kú ojú ò'sùwọn tó àti bí àwọn elétò ààbò ṣe n fọ́wọ́sowọ́pọ̀ pẹ̀lú àwọn ọdaran ìwa àjẹ bánu àti iwa wọ̀ọ̀bìa láàrín ìlú.

Síbẹ̀síbẹ̀, sẹnatọ náà ni ohunkohun to wu kí o fa ti àwọn ajínígbe ṣe n ṣe iru rẹ̀, síbl gbogbo ọmọ Naijria lo wa ninu ewu.

Lẹyin atótónu gbogbo, ìle fi ẹnu ko lórí abádofin naa wọ́n si fi sọwọ si ààrẹ ilé ìgbìms asofin Ahmed Lawan àti ìgbìmọ̀ tèékótó lóri ofin àti ẹ̀tọ́ ọmọniyan fún àwọn