PDP àti APC pín ìjọba ìbílẹ̀ mọ́ ara wọn lọ́wọ́ níbi ètò ìdìbó Abuja, èrò àwọn ọmọ Nàìjíríà ṣọ̀tọ̀ọ̀tọ̀

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 2

Ẹgbẹ́ òṣèlú All Progressives Congress (APC) àti Peoples Democratic Party (PDP) ti pín ìjọba ìbílẹ̀ mẹ́fà tó wà ní olú ìlú ilẹ̀ wa déédé níbi ètò ìdìbò ìjọba ìbílẹ̀ tó wáyé ní òpin ọ̀sẹ̀.

Èyí túmọ̀ sí pé ìjọba ìbílẹ̀ mẹ́ta mẹ́ta ní ẹgbẹ́ méjéèjì ní ìkápá lé lórí báyìí.

Ẹgbẹ́ òṣèlú PDP ló gbégbá orékè ní ìọba ìbílẹ̀ AMAC, níbi tí ilé ìjọba wà, Bwari and Kuje.

Ní àwọn ìjọba ìbílẹ̀ Gwagwalada, Kwali àti Abaji ni ẹgbẹ́ òṣèlú APC ti mókè.

Ìbò ẹgbẹ́ òṣèlú APC:

Ní Gwagwalada, alága ìjọba ìbílẹ̀ tó wà nípò tẹ́lẹ̀ lábẹ́ àsíá ẹgbẹ́ òṣèlú APC, Jibrin Abubakar padà sípò nígbà tó fẹ́yìn akẹgbẹ́ rẹ̀ lẹ́gbẹ́ òṣèlú PDP janlè pẹ̀lú ìbò 11,125 sí 9,597.

Ìbò ọ̀dúnrún lé ẹyọ kan ni Danladi Chiya tí òun náà ń padà sí ipò náà, fi na Haruna Pai láti di alága ìjọba ìbílẹ̀ Kwali.

Ẹ̀wẹ̀, ní ìjọba ìbílẹ̀ Abaji, ẹgbẹ́ òṣèlú APC wọlé ìbò ṣùgbọ́n wọn kò ní olùdíje kan gbòógì nítorí àwọn méjì ń ṣe ìfaǹfà lórí ta ni yóò gbé àsíá ẹgbẹ́ náà.

Ìbò ẹgbẹ́ òṣèlú PDP

Ní ìjọba ìbílẹ̀ Bwari, John Gabaya gbégbá orékè níbi bó ṣe kó ìbò 13,045 lòdì sí ìbò 7,697 tí Haruna Shekwolo ti ẹgbẹ́ APC kó.

Suleiman Sabo, jáwé olúborí ìjọba ìbílẹ̀ Kuje pẹ̀lú ìbò 13,301 bó ṣe fẹ̀yìn Sarki Hamidu ẹgbẹ́ òṣèlú APC janlẹ̀ pẹ̀lú ìbò 7,694.

Ní ìjọba ìbílẹ̀ AMAC, Christopher Zakka kó ìbò 19,302 nínú ìbò 34,675 tí wọ́n dí ní ìjọba ìbílẹ̀ náà.

Kini awọn eeyan n sọ nipa idibo naa?

Bi awọn kan ṣe n bẹnu ẹ̀tẹ́ lu bi ero pupọ ko ṣe jade dibo ni Abuja ni awọn mii n ni ko dara to lati maa fi ẹnu